1. Kíyè sí i, nígbàkígbà tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” dípò “ẹyọ” fún ara Rẹ̀, kò túmọ̀ sí pé “Ọlọ́hun Òdodo” pọ̀ ní òǹkà. Ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ọ̀pọ̀ lè dúró fún ọ̀pọ̀ ní òǹkà tàbí àpọ́nlé.
1. Ibn ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí i - sọ pé: “Nínú èdè ‘Abrāniyyah (Hébérù), “’Isrọ̄” túmọ̀ sí “ẹrú”, “ ’īl” sì túmọ̀ sí “Allāhu”. Èyí já sí pé, “ẹrú Allāhu” ni ìtúmọ̀ “’Isrọ̄’īl”. (Tọbariy)
1. Títa āyah Taorāt àti ’Injīl ní owó pọ́ọ́kú ni títi ọwọ́ bọ̀ ọ́ lójú nítorí kí wọ́n lè jáde kúrò lábẹ́ òfin Allāhu fún ìgbádùn ayé.
1. Mẹ́ta ni sùúrù yìí pín sí. Ìkíní: Dídúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn ’Islām. Ìkejì: Ṣíṣe ìfaradà lórí àdánwò àti níní àtẹ̀mọ́ra ìnira. Ìkẹta: Sísá fún ẹ̀ṣẹ̀.
1. Ìyẹn ni pé, l’ọ́jọ́ Àjíǹde dúkìá kan kan kò níí wúlò fún ìràpadà ẹ̀mí níbi Iná àfi iṣẹ́ rere tí í ṣe ìjọ́sìn fún Allāhu àti ìwà rere tó tọ sunnah.