1. Àdéhùn yìí wáyé láààrin Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn yẹhudi ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí āyah 85 ṣe fi rinlẹ̀, àwọn yẹhudi gbàbọ̀dè, wọ́n sì lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn Ƙuraeṣi tí wọ́n wá gbé ogun ti àwọn mùsùlùmí ní ìlú Mọdīnah.
1.Ibn Kathīr sọ pé, “Wọ́n fẹ́ràn ayé ju ọ̀run, wọ́n sì ṣa ayé lẹ́ṣà ju ọ̀run.”
1. Ìyẹn ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Allāhu fún un.