Kilniojo Korano reikšmių vertimas - Vertimas į jorubų k. - Abu Rahima Mikail

Puslapio numeris:close

external-link copy
118 : 9

وَعَلَى ٱلثَّلَٰثَةِ ٱلَّذِينَ خُلِّفُواْ حَتَّىٰٓ إِذَا ضَاقَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلۡأَرۡضُ بِمَا رَحُبَتۡ وَضَاقَتۡ عَلَيۡهِمۡ أَنفُسُهُمۡ وَظَنُّوٓاْ أَن لَّا مَلۡجَأَ مِنَ ٱللَّهِ إِلَّآ إِلَيۡهِ ثُمَّ تَابَ عَلَيۡهِمۡ لِيَتُوبُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ

(Ó tún gba ìronúpìwàdà) àwọn mẹ́ta tí A so ọ̀rọ̀ gbígba ìronúpìwàdà wọn rọ̀ (nínú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Tabūk. Àwọn mùsùlùmí dẹ́yẹ sí wọn) títí ilẹ̀ fi fún mọ́ wọn tòhun ti bí ó ṣe fẹjú tó. Ọ̀rọ̀ ara wọn sì ṣú ara wọn. Wọ́n sì mọ̀ (ní àmọ̀dájú) pé kò sí ibùsásí kan tí àwọn fi lè sá mọ́ Allāhu lọ́wọ́ àfi kí wọ́n sá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn nítorí kí wọ́n lè máa ronú pìwàdà. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
119 : 9

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَكُونُواْ مَعَ ٱلصَّٰدِقِينَ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wà pẹ̀lú àwọn olódodo. info
التفاسير:

external-link copy
120 : 9

مَا كَانَ لِأَهۡلِ ٱلۡمَدِينَةِ وَمَنۡ حَوۡلَهُم مِّنَ ٱلۡأَعۡرَابِ أَن يَتَخَلَّفُواْ عَن رَّسُولِ ٱللَّهِ وَلَا يَرۡغَبُواْ بِأَنفُسِهِمۡ عَن نَّفۡسِهِۦۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ لَا يُصِيبُهُمۡ ظَمَأٞ وَلَا نَصَبٞ وَلَا مَخۡمَصَةٞ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَا يَطَـُٔونَ مَوۡطِئٗا يَغِيظُ ٱلۡكُفَّارَ وَلَا يَنَالُونَ مِنۡ عَدُوّٖ نَّيۡلًا إِلَّا كُتِبَ لَهُم بِهِۦ عَمَلٞ صَٰلِحٌۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ará ìlú Mọdīnah àti ẹni tí ó wà ní àyíká wọn nínú àwọn Lárúbáwá oko láti sá sẹ́yìn fún Òjíṣẹ́ Allāhu (nípa ogun ẹ̀sìn. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn) láti fẹ́ràn ẹ̀mí ara wọn ju ẹ̀mí rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú òǹgbẹ, ìnira àti ebi kan kò níí ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ojú-ọ̀nà Allāhu (lójú ogun), wọn kò sì níí tẹ ọ̀nà kan tí ń bí àwọn aláìgbàgbọ́ nínú, àti pé ọwọ́ wọn kò níí ba kiní kan lára ọ̀tá (yálà ọrọ̀ ogun tàbí ẹ̀mí wọn) àfi kí wọ́n fi kọ iṣẹ́ rere sílẹ̀ fún wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre. info
التفاسير:

external-link copy
121 : 9

وَلَا يُنفِقُونَ نَفَقَةٗ صَغِيرَةٗ وَلَا كَبِيرَةٗ وَلَا يَقۡطَعُونَ وَادِيًا إِلَّا كُتِبَ لَهُمۡ لِيَجۡزِيَهُمُ ٱللَّهُ أَحۡسَنَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Wọn kò sì níí ná owó kékeré tàbí púpọ̀ (fún ogun ẹ̀sìn), tàbí kí wọ́n la àfonífojì kan kọ já àfi kí wọ́n kọ ọ́ sílẹ̀ fún wọn nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
122 : 9

۞ وَمَا كَانَ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ لِيَنفِرُواْ كَآفَّةٗۚ فَلَوۡلَا نَفَرَ مِن كُلِّ فِرۡقَةٖ مِّنۡهُمۡ طَآئِفَةٞ لِّيَتَفَقَّهُواْ فِي ٱلدِّينِ وَلِيُنذِرُواْ قَوۡمَهُمۡ إِذَا رَجَعُوٓاْ إِلَيۡهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَحۡذَرُونَ

Àwọn mùsùlùmí kò ní láti tú jáde tán nílé pátápátá. Èé ṣe tí igun kan nínú wọn nínú ikọ̀ kọ̀ọ̀kan kò fi jáde láti wá àgbọ́yé ìmọ̀ nípa ẹ̀sìn, kí wọ́n sì máa ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn wọn nígbà tí wọ́n bá padà sọ́dọ̀ wọn nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra ṣe. info
التفاسير: