1. Ìyẹn àwọn Yẹhudi ọmọ Nadīr.
1. Ìyẹn ni pé, tí àwọn onítírà kò bá fi ìlú Mọdīnah sílẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí ni, ẹ̀mí wọn ìbá lọ sí i nítorí pé, wọ́n ti da àwọn mùsùlùmí.
1. Ìyẹn ni pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun ẹ̀sìn kò sí fún bíba àwọn dúkìá ọ̀tá ẹ̀sìn jẹ́, èyí tí ó bá padà bàjẹ́ nínú àwọn dúkìá náà kò níí di ọ̀ràn sí ìjọ mùsùlùmí lọ́rùn ní ọ̀run nítorí pé, kò sí bí ogun ẹ̀sìn ṣe lè ṣẹlẹ̀ tí àwọn dúkìá kan kò níí bàjẹ́.
1. Ìyẹn ni pé, àwọn ọmọ ìlú Mọdīnah, tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ òdodo ṣíwájú kí àwọn mùsùlùmi tó ṣe hijrah wá bá wọn.
1. Àdúà kan nìyí tí a lè máa fi tọrọ àforíjìn ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn òkú mùsùlùmí.
1. Ìyẹn ni pé, tí àwọn mùsùlùmí bá lé àwọn yẹhudi jáde kúrò nínú ìlú Mọdīnah, àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò níí jáde pẹ̀lú àwọn yẹhudi. Wọ́n kàn ń tàn wọ́n lásán ni.