Kilniojo Korano reikšmių vertimas - Vertimas į jorubų k. - Abu Rahima Mikail

Puslapio numeris:close

external-link copy
75 : 4

وَمَا لَكُمۡ لَا تُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلۡمُسۡتَضۡعَفِينَ مِنَ ٱلرِّجَالِ وَٱلنِّسَآءِ وَٱلۡوِلۡدَٰنِ ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَآ أَخۡرِجۡنَا مِنۡ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلظَّالِمِ أَهۡلُهَا وَٱجۡعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ وَلِيّٗا وَٱجۡعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ نَصِيرًا

Kí l’ó ṣe yín tí ẹ kò níí jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn Rẹ̀) àti (fún ààbò) àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú ìlú yìí, ìlú àwọn alábòsí. Fún wa ní aláàbò kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ́. Kí Ó sì fún wa ní alárànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ.” info
التفاسير:

external-link copy
76 : 4

ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱلطَّٰغُوتِ فَقَٰتِلُوٓاْ أَوۡلِيَآءَ ٱلشَّيۡطَٰنِۖ إِنَّ كَيۡدَ ٱلشَّيۡطَٰنِ كَانَ ضَعِيفًا

Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń jagun sí ojú-ọ̀nà òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ja àwọn ọ̀rẹ́ aṣ-Ṣaetọ̄n lógun. Dájúdájú ète aṣ-Ṣaetọ̄n, ó jẹ́ ohun tí ó lẹ. info
التفاسير:

external-link copy
77 : 4

أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ قِيلَ لَهُمۡ كُفُّوٓاْ أَيۡدِيَكُمۡ وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقِتَالُ إِذَا فَرِيقٞ مِّنۡهُمۡ يَخۡشَوۡنَ ٱلنَّاسَ كَخَشۡيَةِ ٱللَّهِ أَوۡ أَشَدَّ خَشۡيَةٗۚ وَقَالُواْ رَبَّنَا لِمَ كَتَبۡتَ عَلَيۡنَا ٱلۡقِتَالَ لَوۡلَآ أَخَّرۡتَنَآ إِلَىٰٓ أَجَلٖ قَرِيبٖۗ قُلۡ مَتَٰعُ ٱلدُّنۡيَا قَلِيلٞ وَٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لِّمَنِ ٱتَّقَىٰ وَلَا تُظۡلَمُونَ فَتِيلًا

Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A sọ fún pé: “Ẹ káwọ́ ró (ẹ má ì jagun ẹ̀sìn, àmọ́) ẹ máa kírun, kí ẹ sì máa yọ Zakāh.” Ṣùgbọ́n nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí, ìgbà náà ni apá kan nínú wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn bí ẹni tí ń bẹ̀rù Allāhu tàbí tí ìbẹ̀rù rẹ̀ le koko jùlọ. Wọ́n sì wí pé: “Olúwa wa, nítorí kí ni O fi ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wa lórí? Kúkú lọ́ wa lára di ìgbà díẹ̀ sí i.[1]” Sọ pé: “Bín-íntín ní ìgbádùn ayé, ọ̀run lóore jùlọ fún ẹni tó bá bẹ̀rù Allāhu. Wọn kò sì níí fi (ohun tó tó) ìbójú kóró èso dàbínù ṣàbòsí sí yín.”² info

1. Ìyẹn ni pé, Ìwọ ìbá má ì sọ ogun ẹ̀sìn di ọ̀ran-anyàn fún wa, bóyá ẹ̀mí wa ìbá gùn sí i, àwa ìbá sí jáyé pẹ́. 2. Ìyẹn ni pé, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní ẹ̀san ọ̀run, kò níí dín rárá.

التفاسير:

external-link copy
78 : 4

أَيۡنَمَا تَكُونُواْ يُدۡرِككُّمُ ٱلۡمَوۡتُ وَلَوۡ كُنتُمۡ فِي بُرُوجٖ مُّشَيَّدَةٖۗ وَإِن تُصِبۡهُمۡ حَسَنَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِكَۚ قُلۡ كُلّٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ فَمَالِ هَٰٓؤُلَآءِ ٱلۡقَوۡمِ لَا يَكَادُونَ يَفۡقَهُونَ حَدِيثٗا

Ibikíbi tí ẹ bá wà, ikú yóò pàdé yín, ẹ̀yin ìbáà wà nínú odi ilé orí òkè ilé gíga fíofío. Tí oore (ìkógun) kan bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Tí aburú (ìfọ́gun) kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Sọ pé: “Gbogbo rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kí ló ń ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí ná, tí wọn kò fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan. info
التفاسير:

external-link copy
79 : 4

مَّآ أَصَابَكَ مِنۡ حَسَنَةٖ فَمِنَ ٱللَّهِۖ وَمَآ أَصَابَكَ مِن سَيِّئَةٖ فَمِن نَّفۡسِكَۚ وَأَرۡسَلۡنَٰكَ لِلنَّاسِ رَسُولٗاۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدٗا

Ohunkóhun tó bá tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ nínú oore, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Ohunkóhun tí ó bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú aburú, láti ọ̀dọ̀ ara rẹ ni. A rán ọ níṣẹ́ pé kí o jẹ́ Òjíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.[1] info

1. Èbùbù, àyànmọ́ àti kádàrá ń túmọ̀ ara wọn. Ohun rere tí ó máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ àti aburú tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá láyé àti lọ́run pẹ̀lú ọ̀nà tí ó máa gbà ṣẹlẹ̀ ni kìkìdá kádàrá ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.

التفاسير: