Kilniojo Korano reikšmių vertimas - Vertimas į jorubų k. - Abu Rahima Mikail

Al-Mu'minuun

external-link copy
1 : 23

قَدۡ أَفۡلَحَ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ

Dájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 23

ٱلَّذِينَ هُمۡ فِي صَلَاتِهِمۡ خَٰشِعُونَ

Àwọn tó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn, info
التفاسير:

external-link copy
3 : 23

وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَنِ ٱللَّغۡوِ مُعۡرِضُونَ

àti àwọn tó ń ṣẹ́rí kúrò níbi ìsọkúsọ, info
التفاسير:

external-link copy
4 : 23

وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِلزَّكَوٰةِ فَٰعِلُونَ

àti àwọn tó ń ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí àti ara) wọn.[1] info

1. Ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí nìyí: “àti àwọn tó ń yọ zakāh”.

التفاسير:

external-link copy
5 : 23

وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ

àti àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn, info
التفاسير:

external-link copy
6 : 23

إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ

àfi ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó wọn àti ẹrúbìnrin wọn. Dájúdájú wọn kì í ṣe ẹni èébú (tí wọ́n bá súnmọ́ wọn), info
التفاسير:

external-link copy
7 : 23

فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ

nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wá òmíràn (súnmọ́) lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà,[1] info

1. Lára wíwá òmíràn súnmọ́ yàtọ̀ sí ìyàwó àti ẹrúbìnrin ni sísúnmọ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ’Islām ṣe ní èèwọ̀ fúnni láti fẹ́ (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ní sūrah an-Nisā’; 4: 22-24), sísúnmọ́ ẹranko, ìbásùn láààrin ọkùnrin méjì, ìbásùn láààrin obìnrin méjì, fífí ọwọ́ fa àtọ̀-ẹni jáde. Kíyè sí i, ọ̀tọ̀ ni ẹrú, ọ̀tọ̀ ni ọmọ-ọ̀dọ̀. Ẹrúbìnrin ni olówó-ẹrú lè fi tura, kì í ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀.

التفاسير:

external-link copy
8 : 23

وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ

àti àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn, info
التفاسير:

external-link copy
9 : 23

وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَوَٰتِهِمۡ يُحَافِظُونَ

àti àwọn tó ń ṣọ́ ìrun wọn; info
التفاسير:

external-link copy
10 : 23

أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡوَٰرِثُونَ

àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùjogún, info
التفاسير:

external-link copy
11 : 23

ٱلَّذِينَ يَرِثُونَ ٱلۡفِرۡدَوۡسَ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ

àwọn tó máa jogún ọgbà ìdẹ̀ra Firdaos. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 23

وَلَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِن سُلَٰلَةٖ مِّن طِينٖ

Dájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú ẹrẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 23

ثُمَّ جَعَلۡنَٰهُ نُطۡفَةٗ فِي قَرَارٖ مَّكِينٖ

Lẹ́yìn náà, A ṣe é ní àtọ̀ sínú àyè ìrọ̀rùn kan (ìyẹn, ilé-ọmọ). info
التفاسير:

external-link copy
14 : 23

ثُمَّ خَلَقۡنَا ٱلنُّطۡفَةَ عَلَقَةٗ فَخَلَقۡنَا ٱلۡعَلَقَةَ مُضۡغَةٗ فَخَلَقۡنَا ٱلۡمُضۡغَةَ عِظَٰمٗا فَكَسَوۡنَا ٱلۡعِظَٰمَ لَحۡمٗا ثُمَّ أَنشَأۡنَٰهُ خَلۡقًا ءَاخَرَۚ فَتَبَارَكَ ٱللَّهُ أَحۡسَنُ ٱلۡخَٰلِقِينَ

Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.[1] Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà). info

1. Ìyẹn ni pé, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn tí ó ní ẹ̀mí, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà sókè bẹ̀rẹ̀ láti òpóǹló títí di ọjọ́ ikú.

التفاسير:

external-link copy
15 : 23

ثُمَّ إِنَّكُم بَعۡدَ ذَٰلِكَ لَمَيِّتُونَ

Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìyẹn, dájúdájú ẹ̀yin yóò di òkú. info
التفاسير:

external-link copy
16 : 23

ثُمَّ إِنَّكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ تُبۡعَثُونَ

Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní Ọjọ́ Àjíǹde wọ́n máa gbe yín dìde. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 23

وَلَقَدۡ خَلَقۡنَا فَوۡقَكُمۡ سَبۡعَ طَرَآئِقَ وَمَا كُنَّا عَنِ ٱلۡخَلۡقِ غَٰفِلِينَ

Dájúdájú A dá àwọn sánmọ̀ méje sí òkè yín. Àwa kò sì níí dágunlá sí àwọn ẹ̀dá. info
التفاسير: