1. Àwọn onisūfī lérò pé āyah yìí ń ṣe é ní èèwọ̀ fún ẹnikẹ́ni láti lé àwọn kúrò nínú mọ́sálásì tàbí láti kọ̀ fún wọn láti ṣe wiridi wọn àti waṭḥīfah wọn nínú mọ́sálásí. Rárá o. Āyah yìí kò gba bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹni tí kò jẹ́ kí àwa mùsùlùmí ṣe ìjọ́sìn tó tọ sunnah nínú mọ́sálásí ni Allāhu pè ní alábòsí jùlọ nínú āyah yìí, kì í ṣe ẹni tí ó kọ aburú àti bidiah ṣíṣe nínú àwọn mọ́sálásí. Ọ̀nà tí àwọn oníwírìdí ń gbà ṣe ìrántí Allāhu kò tọ sunnah rárá. Dandan sì ni fún wa láti lé wọn kúrò nínú mọ́sálásí Allāhu. “Zāwiyah” ni wọ́n máa ń kọ́ fún wírìdí bid‘ah, kì í ṣe mọ́sálásí.
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ti fi sūrah al-Baƙọrah; 2:144, 149, àti 150 pa ìdájọ́ āyah yìí rẹ́, ìdájọ́ tí ń bẹ nínú āyah náà ṣe é lò fún ẹni tí ó wà ní àyè kan tí kò sì mọ agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú náà láààrin orígun ayé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nínú ìlú náà. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí kírun rẹ̀ láààrin orígun méjì nínú orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìlú rẹ̀ tí gbé e títí ó máa fi mọ àmọ̀dájú nípa agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú rẹ̀.
1. Àṣẹ Allāhu lórí ẹ̀dá pín sí ọ̀nà méjì gbòòrò. Ìkíní: ’amr ṣẹr‘iy “àṣẹ tẹ̀sìn” àti ’amr kaoniy “àṣẹ tayé”. Àwọn mọlāika àti àwọn mùsùlùmí nìkan ló ń tẹ̀lé àwọn àṣẹ méjèèjì. Àmọ́ àṣẹ tayé nìkan ṣoṣo ni àwọn aláìgbàgbọ́ ń tẹ̀lé. Ìyẹn sì ni àṣẹ tí kádàrá bá mú wá. Ìyẹn ni pé, ohun tí Allāhu bá fẹ́ fi ẹ̀dá Rẹ̀ rọ ló máa fi rọ, jíjẹ́ aláìgbàgbọ́ ẹ̀dá náà kò lè dí I lọ́wọ́.