1. Ìrìn-àjò òru tí Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - mú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rìn yìí, kì í ṣe nípasẹ̀ àlá lílá, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí àti ara.
1. Ìbàjẹ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ìsọ ti ìkìlọ̀, òhun ni pípa tí wọ́n máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Zakariyyā - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti pípa tí wọ́n tún máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Yahyā - kí ọlà Allāhu máa bá a -.
1. Ìyẹn ni pé, nígbà tí àsìkò ìyà bá tó fún wọn lórí ìbàjẹ́ wọn tí wọ́n á ṣe nígbà àkọ́kọ́.