وه‌رگێڕانی ماناكانی قورئانی پیرۆز - وەرگێڕاوی یورباوی - ئەبو رەحیمە میكائیل

external-link copy
180 : 7

وَلِلَّهِ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰ فَٱدۡعُوهُ بِهَاۖ وَذَرُواْ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ أَسۡمَٰٓئِهِۦۚ سَيُجۡزَوۡنَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Ti Allāhu ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi pè É. Kí ẹ sì pa àwọn tó ń darí àwọn orúkọ Rẹ̀ kọ ọ̀nà òdì tì.[1] A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́. info

1. Ẹni tí ó ń dárí àwọn orúkọ Allāhu - tó ga jùlọ - kọ ọ̀nà òdì ni ẹni tí ó ń sọ pé, "wọ́n yọ àwọn orúkọ òrìṣà kan jáde láti ara àwọn orúkọ Allāhu tó dára jùlọ àti àwọn ìròyìn Rẹ̀ tó ga jùlọ." Ẹni tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ti bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ó ti ṣẹbọ.

التفاسير: