وه‌رگێڕانی ماناكانی قورئانی پیرۆز - وەرگێڕاوی یورباوی - ئەبو رەحیمە میكائیل

Al-Haaqqah

external-link copy
1 : 69

ٱلۡحَآقَّةُ

Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà! info
التفاسير:

external-link copy
2 : 69

مَا ٱلۡحَآقَّةُ

Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà? info
التفاسير:

external-link copy
3 : 69

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحَآقَّةُ

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà? info
التفاسير:

external-link copy
4 : 69

كَذَّبَتۡ ثَمُودُ وَعَادُۢ بِٱلۡقَارِعَةِ

Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.[1] info

1. Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ Àjíǹde ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà àti Ajámọláyà bí àrá.

التفاسير:

external-link copy
5 : 69

فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهۡلِكُواْ بِٱلطَّاغِيَةِ

Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 69

وَأَمَّا عَادٞ فَأُهۡلِكُواْ بِرِيحٖ صَرۡصَرٍ عَاتِيَةٖ

Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 69

سَخَّرَهَا عَلَيۡهِمۡ سَبۡعَ لَيَالٖ وَثَمَٰنِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومٗاۖ فَتَرَى ٱلۡقَوۡمَ فِيهَا صَرۡعَىٰ كَأَنَّهُمۡ أَعۡجَازُ نَخۡلٍ خَاوِيَةٖ

Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù tó ti luhò nínú ni wọ́n.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Fussilat; 41:16.

التفاسير:

external-link copy
8 : 69

فَهَلۡ تَرَىٰ لَهُم مِّنۢ بَاقِيَةٖ

Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn tó ṣẹ́ kù bí? info
التفاسير: