وه‌رگێڕانی ماناكانی قورئانی پیرۆز - وەرگێڕاوی یورباوی - ئەبو رەحیمە میكائیل

Koof

external-link copy
1 : 50

قٓۚ وَٱلۡقُرۡءَانِ ٱلۡمَجِيدِ

Ƙọ̄f. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] (Allāhu fi) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé búra. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

التفاسير:

external-link copy
2 : 50

بَلۡ عَجِبُوٓاْ أَن جَآءَهُم مُّنذِرٞ مِّنۡهُمۡ فَقَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ هَٰذَا شَيۡءٌ عَجِيبٌ

Ṣùgbọ́n wọ́n ṣèèmọ̀ nítorí pé olùkìlọ̀ kan wá bá wọn láti ààrin ara wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: “Èyí ni ohun ìyanu.” info
التفاسير:

external-link copy
3 : 50

أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗاۖ ذَٰلِكَ رَجۡعُۢ بَعِيدٞ

Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ (ni a óò tún jí dìde padà). Ìyẹn ni ìdápadà tó jìnnà (sí n̄ǹkan tí ó lè ṣẹlẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
4 : 50

قَدۡ عَلِمۡنَا مَا تَنقُصُ ٱلۡأَرۡضُ مِنۡهُمۡۖ وَعِندَنَا كِتَٰبٌ حَفِيظُۢ

Dájúdájú A ti mọ ohun tí ilẹ̀ ń mú jẹ nínú wọn. Tírà (iṣẹ́ ẹ̀dá) tí wọ́n ń ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ Wa. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 50

بَلۡ كَذَّبُواْ بِٱلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمۡ فَهُمۡ فِيٓ أَمۡرٖ مَّرِيجٍ

Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe òdodo (al-Ƙur’ān) ní irọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, wọ́n ti wà nínú ìdààmú. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 50

أَفَلَمۡ يَنظُرُوٓاْ إِلَى ٱلسَّمَآءِ فَوۡقَهُمۡ كَيۡفَ بَنَيۡنَٰهَا وَزَيَّنَّٰهَا وَمَا لَهَا مِن فُرُوجٖ

Ṣé wọn kò wo sánmọ̀ òkè wọn bí A ti ṣe mọ ọ́n pa àti (bí) A ti ṣe ṣe é ní ọ̀ṣọ́, tí kò sì sí àlàfo sísán kan lára rẹ̀? info
التفاسير:

external-link copy
7 : 50

وَٱلۡأَرۡضَ مَدَدۡنَٰهَا وَأَلۡقَيۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ وَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوۡجِۭ بَهِيجٖ

Àti pé ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú oríṣiríṣi irúgbìn tó dára hù jáde láti inú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 50

تَبۡصِرَةٗ وَذِكۡرَىٰ لِكُلِّ عَبۡدٖ مُّنِيبٖ

(Ó jẹ́) àríwòye àti ìrántí fún gbogbo ẹrúsìn tó ń ṣẹ́rí padà (síbi òdodo). info
التفاسير:

external-link copy
9 : 50

وَنَزَّلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ مُّبَٰرَكٗا فَأَنۢبَتۡنَا بِهِۦ جَنَّٰتٖ وَحَبَّ ٱلۡحَصِيدِ

A ń sọ omi ìbùkún kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì ń fi mú àwọn ọgbà oko àti àwọn èso tí wọ́n ń kórè rẹ̀ hù jáde. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 50

وَٱلنَّخۡلَ بَاسِقَٰتٖ لَّهَا طَلۡعٞ نَّضِيدٞ

(A tún mú) igi dàbínù hù ga, tí àwọn èso orí rẹ̀ so jìgbìnnì. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 50

رِّزۡقٗا لِّلۡعِبَادِۖ وَأَحۡيَيۡنَا بِهِۦ بَلۡدَةٗ مَّيۡتٗاۚ كَذَٰلِكَ ٱلۡخُرُوجُ

Arísìkí ni fún àwọn ẹrú (Allāhu). A sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè. Báyẹn ni ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè yó ṣe rí). info
التفاسير:

external-link copy
12 : 50

كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ وَأَصۡحَٰبُ ٱلرَّسِّ وَثَمُودُ

Àwọn ènìyàn (Ànábì) Nūh, àwọn ènìyàn Rass àti àwọn (ènìyàn) Thamūd pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 50

وَعَادٞ وَفِرۡعَوۡنُ وَإِخۡوَٰنُ لُوطٖ

Àti àwọn ‘Ād, Fir‘aon àti àwọn ọmọ ìyá (Ànábì) Lūt, info
التفاسير:

external-link copy
14 : 50

وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡأَيۡكَةِ وَقَوۡمُ تُبَّعٖۚ كُلّٞ كَذَّبَ ٱلرُّسُلَ فَحَقَّ وَعِيدِ

àti àwọn ará ’Aekah àti àwọn ìjọ Tubba‘u; gbogbo wọn pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìlérí Mi sì kò (lórí wọn). info
التفاسير:

external-link copy
15 : 50

أَفَعَيِينَا بِٱلۡخَلۡقِ ٱلۡأَوَّلِۚ بَلۡ هُمۡ فِي لَبۡسٖ مِّنۡ خَلۡقٖ جَدِيدٖ

Ǹjẹ́ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ kó agara bá Wa bí? Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì (àti ìrújú) nípa ìṣẹ̀dá (wọn) ní ọ̀tun ni. info
التفاسير: