وه‌رگێڕانی ماناكانی قورئانی پیرۆز - وەرگێڕاوی یورباوی - ئەبو رەحیمە میكائیل

Ash-Shuaraa'

external-link copy
1 : 26

طسٓمٓ

Tọ̄ sīn mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

التفاسير:

external-link copy
2 : 26

تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ

Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 26

لَعَلَّكَ بَٰخِعٞ نَّفۡسَكَ أَلَّا يَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ

Nítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 26

إِن نَّشَأۡ نُنَزِّلۡ عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ ءَايَةٗ فَظَلَّتۡ أَعۡنَٰقُهُمۡ لَهَا خَٰضِعِينَ

Tí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 26

وَمَا يَأۡتِيهِم مِّن ذِكۡرٖ مِّنَ ٱلرَّحۡمَٰنِ مُحۡدَثٍ إِلَّا كَانُواْ عَنۡهُ مُعۡرِضِينَ

Kò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 26

فَقَدۡ كَذَّبُواْ فَسَيَأۡتِيهِمۡ أَنۢبَٰٓؤُاْ مَا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ

Dájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 26

أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ كَمۡ أَنۢبَتۡنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوۡجٖ كَرِيمٍ

Ṣé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀? info
التفاسير:

external-link copy
8 : 26

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 26

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 26

وَإِذۡ نَادَىٰ رَبُّكَ مُوسَىٰٓ أَنِ ٱئۡتِ ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: “Lọ bá ìjọ alábòsí, info
التفاسير:

external-link copy
11 : 26

قَوۡمَ فِرۡعَوۡنَۚ أَلَا يَتَّقُونَ

ìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé, ‘Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni.’ ” info
التفاسير:

external-link copy
12 : 26

قَالَ رَبِّ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يُكَذِّبُونِ

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 26

وَيَضِيقُ صَدۡرِي وَلَا يَنطَلِقُ لِسَانِي فَأَرۡسِلۡ إِلَىٰ هَٰرُونَ

Ó sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 26

وَلَهُمۡ عَلَيَّ ذَنۢبٞ فَأَخَافُ أَن يَقۡتُلُونِ

Àti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí.” info
التفاسير:

external-link copy
15 : 26

قَالَ كَلَّاۖ فَٱذۡهَبَا بِـَٔايَٰتِنَآۖ إِنَّا مَعَكُم مُّسۡتَمِعُونَ

(Allāhu) sọ pé: “Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín). info
التفاسير:

external-link copy
16 : 26

فَأۡتِيَا فِرۡعَوۡنَ فَقُولَآ إِنَّا رَسُولُ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 26

أَنۡ أَرۡسِلۡ مَعَنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ

(À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ.” info
التفاسير:

external-link copy
18 : 26

قَالَ أَلَمۡ نُرَبِّكَ فِينَا وَلِيدٗا وَلَبِثۡتَ فِينَا مِنۡ عُمُرِكَ سِنِينَ

(Fir‘aon) wí pé: “Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ? info
التفاسير:

external-link copy
19 : 26

وَفَعَلۡتَ فَعۡلَتَكَ ٱلَّتِي فَعَلۡتَ وَأَنتَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ

O sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore.” info
التفاسير:

external-link copy
20 : 26

قَالَ فَعَلۡتُهَآ إِذٗا وَأَنَا۠ مِنَ ٱلضَّآلِّينَ

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláṣìṣe (èmi kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é). info
التفاسير:

external-link copy
21 : 26

فَفَرَرۡتُ مِنكُمۡ لَمَّا خِفۡتُكُمۡ فَوَهَبَ لِي رَبِّي حُكۡمٗا وَجَعَلَنِي مِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Mo sì sá fún yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Lẹ́yìn náà, Allāhu ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 26

وَتِلۡكَ نِعۡمَةٞ تَمُنُّهَا عَلَيَّ أَنۡ عَبَّدتَّ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ

Àti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl di ẹrú (ńkọ́?).[1] info

1. Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ń fọ èsì fún Fir‘aon pé, tí o bá sọ pé o ṣoore alágbàtọ́ fún mi, ṣebí o tún sọ àwọn ènìyàn mi di ẹrú rẹ?!

التفاسير:

external-link copy
23 : 26

قَالَ فِرۡعَوۡنُ وَمَا رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Fir‘aon wí pé: “Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?” info
التفاسير:

external-link copy
24 : 26

قَالَ رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَآۖ إِن كُنتُم مُّوقِنِينَ

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.” info
التفاسير:

external-link copy
25 : 26

قَالَ لِمَنۡ حَوۡلَهُۥٓ أَلَا تَسۡتَمِعُونَ

(Fir‘aon) wí fún àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (tó ń sọ ni)?” info
التفاسير:

external-link copy
26 : 26

قَالَ رَبُّكُمۡ وَرَبُّ ءَابَآئِكُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.” info
التفاسير:

external-link copy
27 : 26

قَالَ إِنَّ رَسُولَكُمُ ٱلَّذِيٓ أُرۡسِلَ إِلَيۡكُمۡ لَمَجۡنُونٞ

(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni.” info
التفاسير:

external-link copy
28 : 26

قَالَ رَبُّ ٱلۡمَشۡرِقِ وَٱلۡمَغۡرِبِ وَمَا بَيۡنَهُمَآۖ إِن كُنتُمۡ تَعۡقِلُونَ

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè.” info
التفاسير:

external-link copy
29 : 26

قَالَ لَئِنِ ٱتَّخَذۡتَ إِلَٰهًا غَيۡرِي لَأَجۡعَلَنَّكَ مِنَ ٱلۡمَسۡجُونِينَ

(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n.” info
التفاسير:

external-link copy
30 : 26

قَالَ أَوَلَوۡ جِئۡتُكَ بِشَيۡءٖ مُّبِينٖ

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan tó yanjú wá fún ọ ńkọ́?” info
التفاسير:

external-link copy
31 : 26

قَالَ فَأۡتِ بِهِۦٓ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ

(Fir‘aon) wí pé: “Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.” info
التفاسير:

external-link copy
32 : 26

فَأَلۡقَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ ثُعۡبَانٞ مُّبِينٞ

Nítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé. info
التفاسير:

external-link copy
33 : 26

وَنَزَعَ يَدَهُۥ فَإِذَا هِيَ بَيۡضَآءُ لِلنَّٰظِرِينَ

Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran. info
التفاسير:

external-link copy
34 : 26

قَالَ لِلۡمَلَإِ حَوۡلَهُۥٓ إِنَّ هَٰذَا لَسَٰحِرٌ عَلِيمٞ

(Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa. info
التفاسير:

external-link copy
35 : 26

يُرِيدُ أَن يُخۡرِجَكُم مِّنۡ أَرۡضِكُم بِسِحۡرِهِۦ فَمَاذَا تَأۡمُرُونَ

Ó fẹ́ fi idán rẹ̀ kó yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”[1] info

1. Fir‘aon sọ gbólóhùn náà, àwọn ìjòyè rẹ̀ náà gbè é lẹ́sẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà sì di àgbàsọ láààrin ara wọn.

التفاسير:

external-link copy
36 : 26

قَالُوٓاْ أَرۡجِهۡ وَأَخَاهُ وَٱبۡعَثۡ فِي ٱلۡمَدَآئِنِ حَٰشِرِينَ

Wọ́n wí pé: “Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ[1] sí àwọn ìlú info

1. Àwọn akójijọ ni àwọn alukoro rẹ̀, àwọn aláago atótó-arére.

التفاسير:

external-link copy
37 : 26

يَأۡتُوكَ بِكُلِّ سَحَّارٍ عَلِيمٖ

(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ.” info
التفاسير:

external-link copy
38 : 26

فَجُمِعَ ٱلسَّحَرَةُ لِمِيقَٰتِ يَوۡمٖ مَّعۡلُومٖ

Wọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
39 : 26

وَقِيلَ لِلنَّاسِ هَلۡ أَنتُم مُّجۡتَمِعُونَ

Wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: “Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí? info
التفاسير:

external-link copy
40 : 26

لَعَلَّنَا نَتَّبِعُ ٱلسَّحَرَةَ إِن كَانُواْ هُمُ ٱلۡغَٰلِبِينَ

Nítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí.” info
التفاسير:

external-link copy
41 : 26

فَلَمَّا جَآءَ ٱلسَّحَرَةُ قَالُواْ لِفِرۡعَوۡنَ أَئِنَّ لَنَا لَأَجۡرًا إِن كُنَّا نَحۡنُ ٱلۡغَٰلِبِينَ

Nígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: “Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?” info
التفاسير:

external-link copy
42 : 26

قَالَ نَعَمۡ وَإِنَّكُمۡ إِذٗا لَّمِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ

(Fir‘aon) wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).” info
التفاسير:

external-link copy
43 : 26

قَالَ لَهُم مُّوسَىٰٓ أَلۡقُواْ مَآ أَنتُم مُّلۡقُونَ

(Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
44 : 26

فَأَلۡقَوۡاْ حِبَالَهُمۡ وَعِصِيَّهُمۡ وَقَالُواْ بِعِزَّةِ فِرۡعَوۡنَ إِنَّا لَنَحۡنُ ٱلۡغَٰلِبُونَ

Wọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: “Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí.” info
التفاسير:

external-link copy
45 : 26

فَأَلۡقَىٰ مُوسَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ تَلۡقَفُ مَا يَأۡفِكُونَ

Nígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló. info
التفاسير:

external-link copy
46 : 26

فَأُلۡقِيَ ٱلسَّحَرَةُ سَٰجِدِينَ

Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu). info
التفاسير:

external-link copy
47 : 26

قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Wọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá, info
التفاسير:

external-link copy
48 : 26

رَبِّ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ

Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.” info
التفاسير:

external-link copy
49 : 26

قَالَ ءَامَنتُمۡ لَهُۥ قَبۡلَ أَنۡ ءَاذَنَ لَكُمۡۖ إِنَّهُۥ لَكَبِيرُكُمُ ٱلَّذِي عَلَّمَكُمُ ٱلسِّحۡرَ فَلَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَۚ لَأُقَطِّعَنَّ أَيۡدِيَكُمۡ وَأَرۡجُلَكُم مِّنۡ خِلَٰفٖ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمۡ أَجۡمَعِينَ

Fir‘aon wí pé: “Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fún yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.” info
التفاسير:

external-link copy
50 : 26

قَالُواْ لَا ضَيۡرَۖ إِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا مُنقَلِبُونَ

(Àwọn òpìdán) sọ pé: “Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa. info
التفاسير:

external-link copy
51 : 26

إِنَّا نَطۡمَعُ أَن يَغۡفِرَ لَنَا رَبُّنَا خَطَٰيَٰنَآ أَن كُنَّآ أَوَّلَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo.”[1] info

1. Ìyẹn ni pé, wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó gba Allāhu gbọ́ nínú ìjọ Fir‘aon. Kì í ṣe pé wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ tó gba Allāhu gbọ́ nínú àwọn ènìyàn.

التفاسير:

external-link copy
52 : 26

۞ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَسۡرِ بِعِبَادِيٓ إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ

A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé), dájúdájú wọn yóò lépa yín.” info
التفاسير:

external-link copy
53 : 26

فَأَرۡسَلَ فِرۡعَوۡنُ فِي ٱلۡمَدَآئِنِ حَٰشِرِينَ

Fir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé): info
التفاسير:

external-link copy
54 : 26

إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَشِرۡذِمَةٞ قَلِيلُونَ

“Dájúdájú àwọn (ọmọ ’Isrọ̄’īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
55 : 26

وَإِنَّهُمۡ لَنَا لَغَآئِظُونَ

Àti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun tó ń bí wa nínú. info
التفاسير:

external-link copy
56 : 26

وَإِنَّا لَجَمِيعٌ حَٰذِرُونَ

Dájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura.” info
التفاسير:

external-link copy
57 : 26

فَأَخۡرَجۡنَٰهُم مِّن جَنَّٰتٖ وَعُيُونٖ

Nítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi, info
التفاسير:

external-link copy
58 : 26

وَكُنُوزٖ وَمَقَامٖ كَرِيمٖ

àti àwọn ilé ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé. info
التفاسير:

external-link copy
59 : 26

كَذَٰلِكَۖ وَأَوۡرَثۡنَٰهَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ

Báyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. info
التفاسير:

external-link copy
60 : 26

فَأَتۡبَعُوهُم مُّشۡرِقِينَ

Wọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ. info
التفاسير:

external-link copy
61 : 26

فَلَمَّا تَرَٰٓءَا ٱلۡجَمۡعَانِ قَالَ أَصۡحَٰبُ مُوسَىٰٓ إِنَّا لَمُدۡرَكُونَ

Nígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú wọn yóò lé wa bá.” info
التفاسير:

external-link copy
62 : 26

قَالَ كَلَّآۖ إِنَّ مَعِيَ رَبِّي سَيَهۡدِينِ

(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí.” info
التفاسير:

external-link copy
63 : 26

فَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنِ ٱضۡرِب بِّعَصَاكَ ٱلۡبَحۡرَۖ فَٱنفَلَقَ فَكَانَ كُلُّ فِرۡقٖ كَٱلطَّوۡدِ ٱلۡعَظِيمِ

A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà án). Ó sì pín (sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀).[1] Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:50.

التفاسير:

external-link copy
64 : 26

وَأَزۡلَفۡنَا ثَمَّ ٱلۡأٓخَرِينَ

A sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn. info
التفاسير:

external-link copy
65 : 26

وَأَنجَيۡنَا مُوسَىٰ وَمَن مَّعَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ

A gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá. info
التفاسير:

external-link copy
66 : 26

ثُمَّ أَغۡرَقۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ

Lẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami). info
التفاسير:

external-link copy
67 : 26

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
68 : 26

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
69 : 26

وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ إِبۡرَٰهِيمَ

Ka ìtàn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn. info
التفاسير:

external-link copy
70 : 26

إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦ مَا تَعۡبُدُونَ

Nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?” info
التفاسير:

external-link copy
71 : 26

قَالُواْ نَعۡبُدُ أَصۡنَامٗا فَنَظَلُّ لَهَا عَٰكِفِينَ

Wọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère òrìṣà kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.” info
التفاسير:

external-link copy
72 : 26

قَالَ هَلۡ يَسۡمَعُونَكُمۡ إِذۡ تَدۡعُونَ

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n? info
التفاسير:

external-link copy
73 : 26

أَوۡ يَنفَعُونَكُمۡ أَوۡ يَضُرُّونَ

Tàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní àǹfààní tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?” info
التفاسير:

external-link copy
74 : 26

قَالُواْ بَلۡ وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا كَذَٰلِكَ يَفۡعَلُونَ

Wọ́n wí pé: “Rárá o! A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni” info
التفاسير:

external-link copy
75 : 26

قَالَ أَفَرَءَيۡتُم مَّا كُنتُمۡ تَعۡبُدُونَ

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “ Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún, info
التفاسير:

external-link copy
76 : 26

أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُمُ ٱلۡأَقۡدَمُونَ

ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín àwọn ẹni ìṣáájú? info
التفاسير:

external-link copy
77 : 26

فَإِنَّهُمۡ عَدُوّٞ لِّيٓ إِلَّا رَبَّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Dájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
78 : 26

ٱلَّذِي خَلَقَنِي فَهُوَ يَهۡدِينِ

(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí; info
التفاسير:

external-link copy
79 : 26

وَٱلَّذِي هُوَ يُطۡعِمُنِي وَيَسۡقِينِ

Ẹni tó ń fún mi ní jíjẹ, tó ń fún mi ní mímu; info
التفاسير:

external-link copy
80 : 26

وَإِذَا مَرِضۡتُ فَهُوَ يَشۡفِينِ

Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn; info
التفاسير:

external-link copy
81 : 26

وَٱلَّذِي يُمِيتُنِي ثُمَّ يُحۡيِينِ

Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè; info
التفاسير:

external-link copy
82 : 26

وَٱلَّذِيٓ أَطۡمَعُ أَن يَغۡفِرَ لِي خَطِيٓـَٔتِي يَوۡمَ ٱلدِّينِ

Ẹni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san. info
التفاسير:

external-link copy
83 : 26

رَبِّ هَبۡ لِي حُكۡمٗا وَأَلۡحِقۡنِي بِٱلصَّٰلِحِينَ

Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere. info
التفاسير:

external-link copy
84 : 26

وَٱجۡعَل لِّي لِسَانَ صِدۡقٖ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ

Fi òdodo sórí ahọ́n àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi nìpa mi (ìyẹn ni pé, jẹ́ kí àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi máa sọ̀rọ̀ mi ní dáadáa).[1] info

1. Allāhu Olùjẹ́pè-ẹ̀dá gba àdúà yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah Mọryam; 19:50.

التفاسير:

external-link copy
85 : 26

وَٱجۡعَلۡنِي مِن وَرَثَةِ جَنَّةِ ٱلنَّعِيمِ

Ṣe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra. info
التفاسير:

external-link copy
86 : 26

وَٱغۡفِرۡ لِأَبِيٓ إِنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلضَّآلِّينَ

Kí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà. info
التفاسير:

external-link copy
87 : 26

وَلَا تُخۡزِنِي يَوۡمَ يُبۡعَثُونَ

Má ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde. info
التفاسير:

external-link copy
88 : 26

يَوۡمَ لَا يَنفَعُ مَالٞ وَلَا بَنُونَ

Ọjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní. info
التفاسير:

external-link copy
89 : 26

إِلَّا مَنۡ أَتَى ٱللَّهَ بِقَلۡبٖ سَلِيمٖ

Àyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́.”[1] info

1. Ọkàn mímọ́ ni ọkàn tí ó là kúrò nínú ẹbọ ṣíṣe, àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ẹ̀sìn.

التفاسير:

external-link copy
90 : 26

وَأُزۡلِفَتِ ٱلۡجَنَّةُ لِلۡمُتَّقِينَ

A máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). info
التفاسير:

external-link copy
91 : 26

وَبُرِّزَتِ ٱلۡجَحِيمُ لِلۡغَاوِينَ

Wọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà, info
التفاسير:

external-link copy
92 : 26

وَقِيلَ لَهُمۡ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡ تَعۡبُدُونَ

wọn yó sì sọ fún wọn pé: “Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?” info
التفاسير:

external-link copy
93 : 26

مِن دُونِ ٱللَّهِ هَلۡ يَنصُرُونَكُمۡ أَوۡ يَنتَصِرُونَ

(N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́? info
التفاسير:

external-link copy
94 : 26

فَكُبۡكِبُواْ فِيهَا هُمۡ وَٱلۡغَاوُۥنَ

Wọ́n sì máa taari gbogbo wọn ṣubú sínú Iná; àwọn (olùṣìnà) àti àwọn ọ̀gá wọn (nínú ìṣìnà), info
التفاسير:

external-link copy
95 : 26

وَجُنُودُ إِبۡلِيسَ أَجۡمَعُونَ

àti àwọn ọmọ ogun ’Iblīs pátápátá. info
التفاسير:

external-link copy
96 : 26

قَالُواْ وَهُمۡ فِيهَا يَخۡتَصِمُونَ

(Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé: info
التفاسير:

external-link copy
97 : 26

تَٱللَّهِ إِن كُنَّا لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ

“A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé info
التفاسير:

external-link copy
98 : 26

إِذۡ نُسَوِّيكُم بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

nígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
99 : 26

وَمَآ أَضَلَّنَآ إِلَّا ٱلۡمُجۡرِمُونَ

Kò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (aṣ-ṣaetọ̄n) ẹlẹ́ṣẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
100 : 26

فَمَا لَنَا مِن شَٰفِعِينَ

Kò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa mọ́. info
التفاسير:

external-link copy
101 : 26

وَلَا صَدِيقٍ حَمِيمٖ

Kò tún sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan (fún wa.) info
التفاسير:

external-link copy
102 : 26

فَلَوۡ أَنَّ لَنَا كَرَّةٗ فَنَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Tí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” info
التفاسير:

external-link copy
103 : 26

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
104 : 26

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
105 : 26

كَذَّبَتۡ قَوۡمُ نُوحٍ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
106 : 26

إِذۡ قَالَ لَهُمۡ أَخُوهُمۡ نُوحٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni? info
التفاسير:

external-link copy
107 : 26

إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín. info
التفاسير:

external-link copy
108 : 26

فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi. info
التفاسير:

external-link copy
109 : 26

وَمَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
110 : 26

فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.” info
التفاسير:

external-link copy
111 : 26

۞ قَالُوٓاْ أَنُؤۡمِنُ لَكَ وَٱتَّبَعَكَ ٱلۡأَرۡذَلُونَ

Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l’ó ń tẹ̀lé ọ!?” info
التفاسير:

external-link copy
112 : 26

قَالَ وَمَا عِلۡمِي بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Ó sọ pé: “Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi). info
التفاسير:

external-link copy
113 : 26

إِنۡ حِسَابُهُمۡ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّيۖ لَوۡ تَشۡعُرُونَ

Kò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura. info
التفاسير:

external-link copy
114 : 26

وَمَآ أَنَا۠ بِطَارِدِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Èmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù. info
التفاسير:

external-link copy
115 : 26

إِنۡ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرٞ مُّبِينٞ

Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.” info
التفاسير:

external-link copy
116 : 26

قَالُواْ لَئِن لَّمۡ تَنتَهِ يَٰنُوحُ لَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمَرۡجُومِينَ

Wọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.” info
التفاسير:

external-link copy
117 : 26

قَالَ رَبِّ إِنَّ قَوۡمِي كَذَّبُونِ

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
118 : 26

فَٱفۡتَحۡ بَيۡنِي وَبَيۡنَهُمۡ فَتۡحٗا وَنَجِّنِي وَمَن مَّعِيَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Nítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” info
التفاسير:

external-link copy
119 : 26

فَأَنجَيۡنَٰهُ وَمَن مَّعَهُۥ فِي ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ

A la òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
120 : 26

ثُمَّ أَغۡرَقۡنَا بَعۡدُ ٱلۡبَاقِينَ

Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn tó ṣẹ́kù lẹ́yìn wọn rì sínú omi. info
التفاسير:

external-link copy
121 : 26

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
122 : 26

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
123 : 26

كَذَّبَتۡ عَادٌ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Àwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
124 : 26

إِذۡ قَالَ لَهُمۡ أَخُوهُمۡ هُودٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni? info
التفاسير:

external-link copy
125 : 26

إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín. info
التفاسير:

external-link copy
126 : 26

فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi. info
التفاسير:

external-link copy
127 : 26

وَمَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
128 : 26

أَتَبۡنُونَ بِكُلِّ رِيعٍ ءَايَةٗ تَعۡبَثُونَ

Ṣé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀? info
التفاسير:

external-link copy
129 : 26

وَتَتَّخِذُونَ مَصَانِعَ لَعَلَّكُمۡ تَخۡلُدُونَ

Ẹ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí). info
التفاسير:

external-link copy
130 : 26

وَإِذَا بَطَشۡتُم بَطَشۡتُمۡ جَبَّارِينَ

Nígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú. info
التفاسير:

external-link copy
131 : 26

فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi. info
التفاسير:

external-link copy
132 : 26

وَٱتَّقُواْ ٱلَّذِيٓ أَمَدَّكُم بِمَا تَعۡلَمُونَ

Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀; info
التفاسير:

external-link copy
133 : 26

أَمَدَّكُم بِأَنۡعَٰمٖ وَبَنِينَ

Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ, info
التفاسير:

external-link copy
134 : 26

وَجَنَّٰتٖ وَعُيُونٍ

àti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi. info
التفاسير:

external-link copy
135 : 26

إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ

Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fún yín.” info
التفاسير:

external-link copy
136 : 26

قَالُواْ سَوَآءٌ عَلَيۡنَآ أَوَعَظۡتَ أَمۡ لَمۡ تَكُن مِّنَ ٱلۡوَٰعِظِينَ

Wọ́n wí pé: “Bákan náà ni fún wa; yálà o ṣe wáàsí fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn oníwáàsí.” info
التفاسير:

external-link copy
137 : 26

إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا خُلُقُ ٱلۡأَوَّلِينَ

- Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́.[1] info

1. Ìyẹn ni pé, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò ní wáàsí lò gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn bàbá ńlá wọn. Irú kan-ùn ni gbogbo wọn.

التفاسير:

external-link copy
138 : 26

وَمَا نَحۡنُ بِمُعَذَّبِينَ

Wọn kò sì níí jẹ wá níyà.” info
التفاسير:

external-link copy
139 : 26

فَكَذَّبُوهُ فَأَهۡلَكۡنَٰهُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ

Nítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
140 : 26

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
141 : 26

كَذَّبَتۡ ثَمُودُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Àwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
142 : 26

إِذۡ قَالَ لَهُمۡ أَخُوهُمۡ صَٰلِحٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni? info
التفاسير:

external-link copy
143 : 26

إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ

Dájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín. info
التفاسير:

external-link copy
144 : 26

فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi. info
التفاسير:

external-link copy
145 : 26

وَمَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
146 : 26

أَتُتۡرَكُونَ فِي مَا هَٰهُنَآ ءَامِنِينَ

Ṣé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀ info
التفاسير:

external-link copy
147 : 26

فِي جَنَّٰتٖ وَعُيُونٖ

nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi. info
التفاسير:

external-link copy
148 : 26

وَزُرُوعٖ وَنَخۡلٖ طَلۡعُهَا هَضِيمٞ

àti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí àwọn èso wọn ti gbó? info
التفاسير:

external-link copy
149 : 26

وَتَنۡحِتُونَ مِنَ ٱلۡجِبَالِ بُيُوتٗا فَٰرِهِينَ

Ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ olùgbéraga! info
التفاسير:

external-link copy
150 : 26

فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi. info
التفاسير:

external-link copy
151 : 26

وَلَا تُطِيعُوٓاْ أَمۡرَ ٱلۡمُسۡرِفِينَ

Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn alákọyọ (aláṣejù), info
التفاسير:

external-link copy
152 : 26

ٱلَّذِينَ يُفۡسِدُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا يُصۡلِحُونَ

àwọn tó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere.” info
التفاسير:

external-link copy
153 : 26

قَالُوٓاْ إِنَّمَآ أَنتَ مِنَ ٱلۡمُسَحَّرِينَ

Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì. info
التفاسير:

external-link copy
154 : 26

مَآ أَنتَ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا فَأۡتِ بِـَٔايَةٍ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ

Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo.” info
التفاسير:

external-link copy
155 : 26

قَالَ هَٰذِهِۦ نَاقَةٞ لَّهَا شِرۡبٞ وَلَكُمۡ شِرۡبُ يَوۡمٖ مَّعۡلُومٖ

Ó sọ pé: “Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀ (ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀). info
التفاسير:

external-link copy
156 : 26

وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوٓءٖ فَيَأۡخُذَكُمۡ عَذَابُ يَوۡمٍ عَظِيمٖ

Ẹ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín.” info
التفاسير:

external-link copy
157 : 26

فَعَقَرُوهَا فَأَصۡبَحُواْ نَٰدِمِينَ

Wọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
158 : 26

فَأَخَذَهُمُ ٱلۡعَذَابُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ

Ìyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
159 : 26

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
160 : 26

كَذَّبَتۡ قَوۡمُ لُوطٍ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Ìjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
161 : 26

إِذۡ قَالَ لَهُمۡ أَخُوهُمۡ لُوطٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni? info
التفاسير:

external-link copy
162 : 26

إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín. info
التفاسير:

external-link copy
163 : 26

فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi. info
التفاسير:

external-link copy
164 : 26

وَمَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
165 : 26

أَتَأۡتُونَ ٱلذُّكۡرَانَ مِنَ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Ṣé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)? info
التفاسير:

external-link copy
166 : 26

وَتَذَرُونَ مَا خَلَقَ لَكُمۡ رَبُّكُم مِّنۡ أَزۡوَٰجِكُمۚ بَلۡ أَنتُمۡ قَوۡمٌ عَادُونَ

Ẹ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fún yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin.” info
التفاسير:

external-link copy
167 : 26

قَالُواْ لَئِن لَّمۡ تَنتَهِ يَٰلُوطُ لَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُخۡرَجِينَ

Wọ́n wí pé: “Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú.” info
التفاسير:

external-link copy
168 : 26

قَالَ إِنِّي لِعَمَلِكُم مِّنَ ٱلۡقَالِينَ

Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùkórira sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín. info
التفاسير:

external-link copy
169 : 26

رَبِّ نَجِّنِي وَأَهۡلِي مِمَّا يَعۡمَلُونَ

Olúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú).” info
التفاسير:

external-link copy
170 : 26

فَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ

Nítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá. info
التفاسير:

external-link copy
171 : 26

إِلَّا عَجُوزٗا فِي ٱلۡغَٰبِرِينَ

Àfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).[1] info

1. Arúgbóbìnrin yẹn ni ìyàwó Ànábì Lūt – kí ọlà Allāhu máa bá a -.

التفاسير:

external-link copy
172 : 26

ثُمَّ دَمَّرۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ

Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run. info
التفاسير:

external-link copy
173 : 26

وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهِم مَّطَرٗاۖ فَسَآءَ مَطَرُ ٱلۡمُنذَرِينَ

A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú. info
التفاسير:

external-link copy
174 : 26

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
175 : 26

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
176 : 26

كَذَّبَ أَصۡحَٰبُ لۡـَٔيۡكَةِ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Àwọn ará ’Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
177 : 26

إِذۡ قَالَ لَهُمۡ شُعَيۡبٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni? info
التفاسير:

external-link copy
178 : 26

إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín. info
التفاسير:

external-link copy
179 : 26

فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi. info
التفاسير:

external-link copy
180 : 26

وَمَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
181 : 26

۞ أَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ وَلَا تَكُونُواْ مِنَ ٱلۡمُخۡسِرِينَ

Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn tó ń dín òṣùwọ̀n kù. info
التفاسير:

external-link copy
182 : 26

وَزِنُواْ بِٱلۡقِسۡطَاسِ ٱلۡمُسۡتَقِيمِ

Ẹ fi ìwọ̀n tó tọ́[1] wọn n̄ǹkan. info

1. Ìyẹn òṣùwọ̀n tí kò tẹ̀ tí kò wọ́.

التفاسير:

external-link copy
183 : 26

وَلَا تَبۡخَسُواْ ٱلنَّاسَ أَشۡيَآءَهُمۡ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ

Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
184 : 26

وَٱتَّقُواْ ٱلَّذِي خَلَقَكُمۡ وَٱلۡجِبِلَّةَ ٱلۡأَوَّلِينَ

Kí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́.” info
التفاسير:

external-link copy
185 : 26

قَالُوٓاْ إِنَّمَآ أَنتَ مِنَ ٱلۡمُسَحَّرِينَ

Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì. info
التفاسير:

external-link copy
186 : 26

وَمَآ أَنتَ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا وَإِن نَّظُنُّكَ لَمِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ

Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a kò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé o wà nínú àwọn òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
187 : 26

فَأَسۡقِطۡ عَلَيۡنَا كِسَفٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ

Nítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo.” info
التفاسير:

external-link copy
188 : 26

قَالَ رَبِّيٓ أَعۡلَمُ بِمَا تَعۡمَلُونَ

Ó sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
189 : 26

فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمۡ عَذَابُ يَوۡمِ ٱلظُّلَّةِۚ إِنَّهُۥ كَانَ عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٍ

Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá. info
التفاسير:

external-link copy
190 : 26

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
191 : 26

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
192 : 26

وَإِنَّهُۥ لَتَنزِيلُ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
193 : 26

نَزَلَ بِهِ ٱلرُّوحُ ٱلۡأَمِينُ

Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ info
التفاسير:

external-link copy
194 : 26

عَلَىٰ قَلۡبِكَ لِتَكُونَ مِنَ ٱلۡمُنذِرِينَ

sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀ info
التفاسير:

external-link copy
195 : 26

بِلِسَانٍ عَرَبِيّٖ مُّبِينٖ

pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé. info
التفاسير:

external-link copy
196 : 26

وَإِنَّهُۥ لَفِي زُبُرِ ٱلۡأَوَّلِينَ

Dájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́. info
التفاسير:

external-link copy
197 : 26

أَوَلَمۡ يَكُن لَّهُمۡ ءَايَةً أَن يَعۡلَمَهُۥ عُلَمَٰٓؤُاْ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ

Ṣé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)?[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:94.

التفاسير:

external-link copy
198 : 26

وَلَوۡ نَزَّلۡنَٰهُ عَلَىٰ بَعۡضِ ٱلۡأَعۡجَمِينَ

Tí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni, info
التفاسير:

external-link copy
199 : 26

فَقَرَأَهُۥ عَلَيۡهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ مُؤۡمِنِينَ

tí ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
200 : 26

كَذَٰلِكَ سَلَكۡنَٰهُ فِي قُلُوبِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ

Báyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
201 : 26

لَا يُؤۡمِنُونَ بِهِۦ حَتَّىٰ يَرَوُاْ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ

Wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro. info
التفاسير:

external-link copy
202 : 26

فَيَأۡتِيَهُم بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ

(Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura. info
التفاسير:

external-link copy
203 : 26

فَيَقُولُواْ هَلۡ نَحۡنُ مُنظَرُونَ

Nígbà náà ni wọn yóò wí pé: “Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí?” info
التفاسير:

external-link copy
204 : 26

أَفَبِعَذَابِنَا يَسۡتَعۡجِلُونَ

Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?[1] info

1. Èsì ni āyah yìí jẹ́ fún āyah 29.

التفاسير:

external-link copy
205 : 26

أَفَرَءَيۡتَ إِن مَّتَّعۡنَٰهُمۡ سِنِينَ

Sọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ! info
التفاسير:

external-link copy
206 : 26

ثُمَّ جَآءَهُم مَّا كَانُواْ يُوعَدُونَ

Lẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní ìlérí fún wọn dé bá wọn. info
التفاسير:

external-link copy
207 : 26

مَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يُمَتَّعُونَ

Ohun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
208 : 26

وَمَآ أَهۡلَكۡنَا مِن قَرۡيَةٍ إِلَّا لَهَا مُنذِرُونَ

A ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
209 : 26

ذِكۡرَىٰ وَمَا كُنَّا ظَٰلِمِينَ

Ìrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí. info
التفاسير:

external-link copy
210 : 26

وَمَا تَنَزَّلَتۡ بِهِ ٱلشَّيَٰطِينُ

Kì í ṣe àwọn aṣ-ṣaetọ̄n ni wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
211 : 26

وَمَا يَنۢبَغِي لَهُمۡ وَمَا يَسۡتَطِيعُونَ

Kò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
212 : 26

إِنَّهُمۡ عَنِ ٱلسَّمۡعِ لَمَعۡزُولُونَ

Dájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀). info
التفاسير:

external-link copy
213 : 26

فَلَا تَدۡعُ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتَكُونَ مِنَ ٱلۡمُعَذَّبِينَ

Nítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà. info
التفاسير:

external-link copy
214 : 26

وَأَنذِرۡ عَشِيرَتَكَ ٱلۡأَقۡرَبِينَ

Kí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ tó súnmọ́ jùlọ. info
التفاسير:

external-link copy
215 : 26

وَٱخۡفِضۡ جَنَاحَكَ لِمَنِ ٱتَّبَعَكَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn tó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
216 : 26

فَإِنۡ عَصَوۡكَ فَقُلۡ إِنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تَعۡمَلُونَ

Tí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú).” info
التفاسير:

external-link copy
217 : 26

وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱلۡعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ

Kí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run; info
التفاسير:

external-link copy
218 : 26

ٱلَّذِي يَرَىٰكَ حِينَ تَقُومُ

Ẹni tó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí) info
التفاسير:

external-link copy
219 : 26

وَتَقَلُّبَكَ فِي ٱلسَّٰجِدِينَ

àti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
220 : 26

إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ

Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
221 : 26

هَلۡ أُنَبِّئُكُمۡ عَلَىٰ مَن تَنَزَّلُ ٱلشَّيَٰطِينُ

Ṣé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn aṣ-ṣaetọ̄n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá fún yín? info
التفاسير:

external-link copy
222 : 26

تَنَزَّلُ عَلَىٰ كُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٖ

Wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
223 : 26

يُلۡقُونَ ٱلسَّمۡعَ وَأَكۡثَرُهُمۡ كَٰذِبُونَ

(Àwọn aṣ-ṣaetọ̄n) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
224 : 26

وَٱلشُّعَرَآءُ يَتَّبِعُهُمُ ٱلۡغَاوُۥنَ

Àwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l’ó ń tẹ̀lé wọn. info
التفاسير:

external-link copy
225 : 26

أَلَمۡ تَرَ أَنَّهُمۡ فِي كُلِّ وَادٖ يَهِيمُونَ

Ṣé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni? info
التفاسير:

external-link copy
226 : 26

وَأَنَّهُمۡ يَقُولُونَ مَا لَا يَفۡعَلُونَ

Àti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe. info
التفاسير:

external-link copy
227 : 26

إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَذَكَرُواْ ٱللَّهَ كَثِيرٗا وَٱنتَصَرُواْ مِنۢ بَعۡدِ مَا ظُلِمُواْۗ وَسَيَعۡلَمُ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ أَيَّ مُنقَلَبٖ يَنقَلِبُونَ

Àfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn tó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí. info
التفاسير: