1. Nígbà tí Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - fi iná wíwọ̀ rínlẹ̀ fún àwọn òrìṣà àti àwọn abọ̀rìṣà wọn, ìyẹn nínú sūrah al-’Ambiyā’; 21:98-100, àwọn abọ̀rìṣà náà bá mú ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - wá gẹ́gẹ́ bí àpẹ̀ẹrẹ òrìṣà àkúnlẹ̀bọ tó máa wọná. Allāhu sì ṣàfọ̀mọ́ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - fúnra Rẹ̀ pé kò sọra rẹ̀ d’òòṣà, àmọ́ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ d’òòṣà nìkan ló máa wọná.