1. Ìyẹn ni pé, kò kó ìnira bá Allāhu láti dá àwọn kèfèrí nìkan kẹ́ ní ilé ayé. Àmọ́ bí Allāhu bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn máa ní àdìsọ́kàn pé, ibi ṣíṣe àìgbàgbọ́ nìkan ni ọrọ̀ ti lè tẹ ènìyàn lọ́wọ́.
1. Àgbọ́yé kìíní ni pé, ìbéèrè náà wáyé nínú ìrìn-àjò òru àti ìgun-sánmọ̀ tí Allāhu mú Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rìn. Àgbọ́yé kejì ni pé, ìbéèrè náà wáyé láààrin Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn tó nímọ̀ nípa Taorāt àti ’Injīl. Ìyẹn ni pé, kí ni àwọn tírà méjèèjì sọ nípa “ta ni a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, ṣé Allāhu ni tàbí àwọn ọlọ́hun mìíràn?”