1. Āyah yìí ń fi kókó pàtàkì kan rinlẹ̀ nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí ayé Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé, ṣíwájú kí ìmísí mímọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀kalẹ̀ fún un kò sí nínú ẹni tó nímọ̀ sí tírà sánmọ̀ kan kan, kò sì dá ìgbàgbọ́ òdodo mọ. Allāhu - tó ga jùlọ - tún fi èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah ad-Duhā; 93:7. Àmọ́ níkété tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bẹ̀rẹ̀ sí gba ìmísí mímọ́, Allāhu fi ìmọ̀ tírà al-Ƙur’ān àti ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀ ọ́n. Ó sì di olùpèpè sínú ìmọ̀nà. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun ni ìṣẹ̀mí ayé wọn rí bí Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ti ṣe rí àfi ẹni tí bàbá rẹ̀ bá jẹ́ Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun.