1. Kíyè sí i, gbólóhùn yìí “Ẹ̀san aburú sì ni aburú bí irú rẹ̀.” kò tako sūrah Fussilat; 41:31. Ìdí ni pé, gbígba ẹ̀san lára alábòsí tàbí gbígba ààrọ̀ kò sọ pé mùsùlùmí kò ní ẹ̀mí àforíjìn, àmọ́ ó lè má nìí agbára láti ṣàmójú kúrò fún alábòsí náà.