1. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ṣe parọ́ ìyàwó gbígbà mọ́ Ànábì Dā’ūd - kí ọlà Allāhu máa bá a -, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe parọ́ pé aṣ-Ṣaetọ̄n àlùjànnú kan gba ìjọba lọ́wọ́ Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Irọ́ burúkú ni èyí. Ìṣe àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì ni irọ́ pípa mọ́ àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -.
1. Gbólóhùn yìí “Èyí ni ọrẹ Wa.” Ó túmọ̀ sí “èyí ni àwọn dúkìá ayé tí A fi ta ọ́ ní ọrẹ”. Ìtúmọ̀ yìí sì ni mo lò. Àmọ́ “Èyí ni ọrẹ Wa.” tún túmọ̀ sí “èyí ni àwọn àlùjànnú tí A fi ta ọ́ ní ọrẹ.”
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’ 4;79.