1. Kíyè sí i, àwọn ìtàn kan tí àwọn nasọ̄rọ̄ máa ń sọ nípa Ànábì Dāwūd - kí ọlà Allāhu máa bá a - pé gbígbà tí ó gba ìyàwó ẹnì kan nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, tí ó fi kún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún ìyàwó tirẹ̀ l’ó bí ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹyọ nínú āyah yìí. Kódà, àwọn tírà tafsīr kan mú ìtàn náà wá pẹ̀lú láì ṣọ̀fín-tótó rẹ̀. Àwọn olùtọpinpin ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kúkú ti tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì sọ pé, “Ìtàn àwọn ọmọ Isrọ̄’īl lásán ni gbogbo rẹ̀. Ìtàn irọ́ ni.