1. Kíyè sí i, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kì í ṣe adéte. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
1. Wọ́n ṣẹ̀dá “mutawaffi” láti ara “wafāt/wafāh.” Ìtúmọ̀ mẹ́ta ni wafāt/wafāh ní nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: “maot” ikú, “naom” oorun àti “ƙọbd” gbígba n̄ǹkan tàbí gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan pátápátá. 2. Lára àṣìṣe àwọn nasọ̄rọ̄ ni bí wọ́n ṣe lérò pé àwọn gan-an ni al-Ƙur’ān ń tọ́ka sí pẹ̀lú gbólóhùn “àwọn tó tẹ̀lé ọ”, ìyẹn àwọn tó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá torí pé ẹlẹ́sìn ’Islām ni àwọn tó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -.
1. Ẹ̀dá Allāhu, ẹrú Allāhu àti Ànábì Allāhu ni àwọn méjèèjì. Àwọn méjèèjì kò sì dìjọ ní bàbá. Kódà Ànábì Ādam kò tún ní ìyá.
1. A lè lo āyah yìí láti fi yanjú àwọn ọ̀ràn kan láààrin àwa mùsùlùmí.