1. Wọ́n ṣẹ̀dá “mutawaffi” láti ara “wafāt/wafāh.” Ìtúmọ̀ mẹ́ta ni wafāt/wafāh ní nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: “maot” ikú, “naom” oorun àti “ƙọbd” gbígba n̄ǹkan tàbí gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan pátápátá. 2. Lára àṣìṣe àwọn nasọ̄rọ̄ ni bí wọ́n ṣe lérò pé àwọn gan-an ni al-Ƙur’ān ń tọ́ka sí pẹ̀lú gbólóhùn “àwọn tó tẹ̀lé ọ”, ìyẹn àwọn tó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá torí pé ẹlẹ́sìn ’Islām ni àwọn tó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -.