ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
56 : 27

۞ فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوۡمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُوٓاْ أَخۡرِجُوٓاْ ءَالَ لُوطٖ مِّن قَرۡيَتِكُمۡۖ إِنَّهُمۡ أُنَاسٞ يَتَطَهَّرُونَ

Kò sí ohun kan tí ìjọ rẹ̀ fọ̀ ní èsì tayọ pé wọ́n wí pé: “Ẹ lé àwọn ènìyàn Lūt jáde kúrò nínú ìlú yín. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn tó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀).” info
التفاسير:

external-link copy
57 : 27

فَأَنجَيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ إِلَّا ٱمۡرَأَتَهُۥ قَدَّرۡنَٰهَا مِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ

Nítorí náà, A gba òun àti ẹbí rẹ̀ là àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ ọ́ pé ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun. info
التفاسير:

external-link copy
58 : 27

وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهِم مَّطَرٗاۖ فَسَآءَ مَطَرُ ٱلۡمُنذَرِينَ

A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú. info
التفاسير:

external-link copy
59 : 27

قُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ وَسَلَٰمٌ عَلَىٰ عِبَادِهِ ٱلَّذِينَ ٱصۡطَفَىٰٓۗ ءَآللَّهُ خَيۡرٌ أَمَّا يُشۡرِكُونَ

Sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Kí àlàáfíà máa bá àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn tí Ó ṣà lẹ́ṣà. Ṣé Allāhu l’Ó lóore jùlọ ni tàbí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀?” info
التفاسير:

external-link copy
60 : 27

أَمَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَنۢبَتۡنَا بِهِۦ حَدَآئِقَ ذَاتَ بَهۡجَةٖ مَّا كَانَ لَكُمۡ أَن تُنۢبِتُواْ شَجَرَهَآۗ أَءِلَٰهٞ مَّعَ ٱللَّهِۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٞ يَعۡدِلُونَ

(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó lóore jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sọ omi kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀, tí A sì fi omi náà hu àwọn ọgbà oko tí ó dára jáde? Kò sì sí agbára fún yín láti mu igi rẹ̀ hù jáde. Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Rárá, ìjọ tó ń ṣẹbọ sí Allāhu ni wọ́n ni. info
التفاسير:

external-link copy
61 : 27

أَمَّن جَعَلَ ٱلۡأَرۡضَ قَرَارٗا وَجَعَلَ خِلَٰلَهَآ أَنۡهَٰرٗا وَجَعَلَ لَهَا رَوَٰسِيَ وَجَعَلَ بَيۡنَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ حَاجِزًاۗ أَءِلَٰهٞ مَّعَ ٱللَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ

(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ibùgbé, tí Ó fi àwọn odò sáààrin rẹ̀, tí Ó fi àwọn àpáta gbagidi sínú ilẹ̀, tí Ó sì fi gàgá sáààrin ibúdò méjèèjì? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
62 : 27

أَمَّن يُجِيبُ ٱلۡمُضۡطَرَّ إِذَا دَعَاهُ وَيَكۡشِفُ ٱلسُّوٓءَ وَيَجۡعَلُكُمۡ خُلَفَآءَ ٱلۡأَرۡضِۗ أَءِلَٰهٞ مَّعَ ٱللَّهِۚ قَلِيلٗا مَّا تَذَكَّرُونَ

(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń jẹ́pè ẹni tí ara ń ni nígbà tí ó bá pè É, tí Ó sì máa gbé aburú kúrò fún un, tí Ó sì ń ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Díẹ̀ ni ohun tí ẹ̀ ń lò nínú ìrántí! info
التفاسير:

external-link copy
63 : 27

أَمَّن يَهۡدِيكُمۡ فِي ظُلُمَٰتِ ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِ وَمَن يُرۡسِلُ ٱلرِّيَٰحَ بُشۡرَۢا بَيۡنَ يَدَيۡ رَحۡمَتِهِۦٓۗ أَءِلَٰهٞ مَّعَ ٱللَّهِۚ تَعَٰلَى ٱللَّهُ عَمَّا يُشۡرِكُونَ

(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń tọ yín sọ́nà nínú àwọn òkùnkùn orí ilẹ̀ àti inú ibúdò, tí Ó tún ń fi atẹ́gùn ránṣẹ́ ní ìró ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Allāhu ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I. info
التفاسير: