ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
36 : 27

فَلَمَّا جَآءَ سُلَيۡمَٰنَ قَالَ أَتُمِدُّونَنِ بِمَالٖ فَمَآ ءَاتَىٰنِۦَ ٱللَّهُ خَيۡرٞ مِّمَّآ ءَاتَىٰكُمۚ بَلۡ أَنتُم بِهَدِيَّتِكُمۡ تَفۡرَحُونَ

Nígbà tí (ìránṣẹ́) dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n, ó sọ pé: “Ṣé ẹ máa fi owó ràn mí lọ́wọ́ ni? Ohun tí Allāhu fún mi lóore jùlọ sí ohun tí Ó fún yín. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin tún ń yọ̀ lórí ẹ̀bùn yín. info
التفاسير:

external-link copy
37 : 27

ٱرۡجِعۡ إِلَيۡهِمۡ فَلَنَأۡتِيَنَّهُم بِجُنُودٖ لَّا قِبَلَ لَهُم بِهَا وَلَنُخۡرِجَنَّهُم مِّنۡهَآ أَذِلَّةٗ وَهُمۡ صَٰغِرُونَ

Padà sí ọ̀dọ̀ wọn. Dájúdájú à ń bọ̀ wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lè kojú rẹ̀. Dájúdájú a máa mú wọn jáde kúrò nínú (ìlú wọn) ní ẹni yẹpẹrẹ, tí wọn yó sì di ẹni àbùkù.” info
التفاسير:

external-link copy
38 : 27

قَالَ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَؤُاْ أَيُّكُمۡ يَأۡتِينِي بِعَرۡشِهَا قَبۡلَ أَن يَأۡتُونِي مُسۡلِمِينَ

(Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èwo nínú yín l’ó máa gbé ìtẹ́ (Bilƙīs) wá bá mi, ṣíwájú kí wọ́n tó wá bá mi (láti di) mùsùlùmí.” info
التفاسير:

external-link copy
39 : 27

قَالَ عِفۡرِيتٞ مِّنَ ٱلۡجِنِّ أَنَا۠ ءَاتِيكَ بِهِۦ قَبۡلَ أَن تَقُومَ مِن مَّقَامِكَۖ وَإِنِّي عَلَيۡهِ لَقَوِيٌّ أَمِينٞ

‘Ifrīt nínú àwọn àlùjànnú sọ pé: “Èmi yóò gbe wá fún ọ ṣíwájú kí o tó dìde kúrò ní ibùjókòó rẹ. Dájúdájú èmi ni alágbára, olùfọkàntán lórí rẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
40 : 27

قَالَ ٱلَّذِي عِندَهُۥ عِلۡمٞ مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ أَنَا۠ ءَاتِيكَ بِهِۦ قَبۡلَ أَن يَرۡتَدَّ إِلَيۡكَ طَرۡفُكَۚ فَلَمَّا رَءَاهُ مُسۡتَقِرًّا عِندَهُۥ قَالَ هَٰذَا مِن فَضۡلِ رَبِّي لِيَبۡلُوَنِيٓ ءَأَشۡكُرُ أَمۡ أَكۡفُرُۖ وَمَن شَكَرَ فَإِنَّمَا يَشۡكُرُ لِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ رَبِّي غَنِيّٞ كَرِيمٞ

Ẹni tí ìmọ̀ kan láti inú tírà wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Èmi yóò gbé e wá fún ọ ṣíwájú kí o tó ṣẹ́jú.” Nígbà tí ó rí i tí ó dé sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Èyí wà nínú oore àjùlọ Olúwa mi láti fi dán mi wò bóyá mo máa dúpẹ́ tàbí mo máa ṣàì moore. Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́ (fún Allāhu), ó dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàìmoore, dájúdájú Olúwa mi ni Ọlọ́rọ̀, Alápọ̀n-ọ́nlé.” info
التفاسير:

external-link copy
41 : 27

قَالَ نَكِّرُواْ لَهَا عَرۡشَهَا نَنظُرۡ أَتَهۡتَدِيٓ أَمۡ تَكُونُ مِنَ ٱلَّذِينَ لَا يَهۡتَدُونَ

Ó sọ pé: “Ẹ pa á lójú dà fún un sí ìrísí mìíràn tí kò fi níí dá a mọ̀, kí á wò ó bóyá ó máa dá a mọ̀ tàbí ó máa wà nínú àwọn tí kò níí dá a mọ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
42 : 27

فَلَمَّا جَآءَتۡ قِيلَ أَهَٰكَذَا عَرۡشُكِۖ قَالَتۡ كَأَنَّهُۥ هُوَۚ وَأُوتِينَا ٱلۡعِلۡمَ مِن قَبۡلِهَا وَكُنَّا مُسۡلِمِينَ

Nígbà tí (Bilƙīs) dé, wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé bí ìtẹ́ rẹ ṣe rí nìyí?” Ó wí pé: "Ó dà bí ẹni pé òhun ni." (Ànábì Sulaemọ̄n sì sọ pé): “Wọ́n ti fún wa ní ìmọ̀ ṣíwájú Bilƙīs. A sì jẹ́ mùsùlùmí.” info
التفاسير:

external-link copy
43 : 27

وَصَدَّهَا مَا كَانَت تَّعۡبُدُ مِن دُونِ ٱللَّهِۖ إِنَّهَا كَانَتۡ مِن قَوۡمٖ كَٰفِرِينَ

Ohun tó ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu sì ṣẹ́rí rẹ̀ (kúrò níbi jíjọ́sìn fún Allāhu). Dájúdájú ó wà nínú ìjọ aláìgbàgbọ́. info
التفاسير:

external-link copy
44 : 27

قِيلَ لَهَا ٱدۡخُلِي ٱلصَّرۡحَۖ فَلَمَّا رَأَتۡهُ حَسِبَتۡهُ لُجَّةٗ وَكَشَفَتۡ عَن سَاقَيۡهَاۚ قَالَ إِنَّهُۥ صَرۡحٞ مُّمَرَّدٞ مِّن قَوَارِيرَۗ قَالَتۡ رَبِّ إِنِّي ظَلَمۡتُ نَفۡسِي وَأَسۡلَمۡتُ مَعَ سُلَيۡمَٰنَ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Wọ́n sọ fún un pé: “Wọ inú ààfin.” Nígbà tí ó rí i, ó ṣe bí ibúdò ni. Ó sì ká aṣọ kúrò ní ojúgun rẹ̀ méjèèjì. (Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Dájúdájú ààfin tí a ṣe rigidin pẹ̀lú díńgí ni.” (Bilƙīs) sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Mo sì di mùsùlùmí pẹ̀lú (Ànábì) Sulaemọ̄n, fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.” info
التفاسير: