1. Āyah yìí kò kó ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - sínú. Ìdí nìyí tí àwọn hadīth tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fi yanjú ọ̀rọ̀ ìpadàbọ̀ rẹ̀ lọ́tọ̀. 2. “àmì kan” nínú āyah yìí dúró fún ìyà kan tàbí ìparun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Òjíṣẹ́ náà.
1. Àgbọ́yé tí ó tẹ̀ṣùwọ̀n jùlọ ni pé, āyah yìí jẹ́ àlàyé fún āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:15.