1. Jíjẹ́ tí Allāhu ń jẹ́ Ọba Àjọkẹ́ ayé ló ń mú ọwọ́ àwọn kèfèrí tẹ oore ayé, kì í ṣe nípasẹ̀ àdúà wọn.
1. “wọ́n fẹ́” dúró fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo; “wọ́n kọ̀” sì dúró fún àwọn munāfiki.
1. Ìtúmọ̀ àkàwé yìí ni pé, òdodo ló ń ṣàǹfààní, òfò ni irọ́.
1. Aburú ìṣírò-iṣẹ́ ni kí Allāhu kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá lé e lọ́wọ́, kí Ó má ṣàforíjìn fún un nítorí pé, ẹ̀dá náà kú sórí ẹbọ ṣíṣe tàbí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu àfọkànṣe.