1. Ànábì Yūsuf - kí ọlà Allāhu máa bá a - kò di ẹlẹ́ṣẹ̀ látara bí èròǹgbà ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ ṣe tì í sínú èròkérò ní ìbámu sí hadīth ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nínú ohun tí ó gbà lẹ́gbàwá làti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ - tó ga jùlọ -. Ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn iṣẹ́ ibi sínú kádàrá. Lẹ́yìn náà, Ó ṣàlàyé èyí (fún ẹ̀dá). Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò iṣẹ́ rere kan, kò sì ṣe é, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere tó pé pérépéré. Tí ó bá sì gbèrò rẹ̀, tí ó sì rí i ṣe, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere mẹ́wàá, títí dé ọgọ́rùn-ún méje àdìpèlé, títí dé àdìpèlé lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò iṣẹ́ ibi kan, kò sì ṣe é, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere tó pé pérépéré (fún gbígbé iṣẹ́ ibi jù sílẹ̀). Tí ó bá sì gbèrò rẹ̀, tí ó sì rí i ṣe, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ ibi ẹyọ kan.” Bukāriy àti Muslim
1. Ẹlẹ́rìí yìí ni ọmọ òpóǹló tí Allāhu - Ọba mímọ́ jùlọ - fún lọ́rọ̀ sọ lórí ìtẹ́. Nítorí náà, kì í ṣe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - nìkan ni ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní òpóǹló lórí ìtẹ́.