1. Ìyẹn ni pé, àwọn ènìyàn kan ń bẹ láààrin àwa mùsùlùmí tí ó jẹ́ pé, tòhun ti bí wọ́n ṣe ń ṣe ’Islām, wọ́n tún ń ṣẹbọ yálà ní kọ̀rọ̀ tàbí ní gban̄gba. Àpẹ̀ẹrẹ àwọn wọ̀nyí ni àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, “mùsùlùmí” tó ń lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, páítọ̀ àti babaláwo, “mùsùlùmí” tí ó ń pe n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu, “mùsùlùmí” tí ó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, “mùsùlùmí” tí ó ń bọ àwọn òrìṣà bí òrìṣà egúngún, òrìṣà ìbejì, òrìṣà Ajé àti “mùsùlùmí” tí ó ń lo ìfúnpá àti àsorọ̀ òògùn àti àsorọ̀ tíà àti “mùsùlùmí” tí ó ń gbé ẹbọ àti ètùtù. Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì í ṣe mùsùlùmí ní ọ̀dọ̀ Allāhu - Ọba mímọ́ jùlọ.
1. Ìyẹn ni pé, bí obìnrin kan bá sọ pé Allāhu ló rán òun ní iṣẹ́ ìránṣẹ́, òpùrọ́ ni.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:114.