1. Ìyẹn ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán àti ìparí ọ̀sán. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán dúró fún lílà al-fajr fún ìrun Subh. Ìparí ọ̀sán dúró fún ìrun Ṭḥuhr àti ‘Asr. 2. Ìyẹn ni abala ìbẹ̀rẹ̀ òru. Èyí dúró fún ìrun Mọgrib àti ‘Iṣā’.
1. Àwọn kan sọ pé, a tún lè túmọ̀ āyah yìí kan náà báyìí pé, “Allāhu kì í pa àwọn ìlú run fún wí pé wọ́n ń ṣẹbọ sí I, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ará ìlú náà bá ń ṣe déédé láààrin ara wọn.” (Tọbariy)