1. Wọ́n kò jẹ́pè Ànábì Ṣua‘eb - kí ọlà Allāhu máa bá a - fún ìdí méjì. Ìkíní: wọ́n ti mọ̀ pé ẹni tí ó bá gbà láti máa kírun kò gbọ́dọ̀ ṣẹbọ mọ́. Ìkejì: wọ́n ti mọ̀ pé ẹni tí ó bá gbà láti máa kírun gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún àwọn ọ̀nà owó harām àti ọ̀nà ìnáwó harām. Èyí sì ni òdodo nípa ẹ̀sìn 'Islām níwọ̀n ìgbà tí mùsùlùmí bá ti fẹ́ jèrè ẹ̀sìn rẹ̀.