クルアーンの対訳 - ヨルバ語対訳 - Abu Rahima Mikhail

Al-Qiyaamah

external-link copy
1 : 75

لَآ أُقۡسِمُ بِيَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ

Èmi (Allāhu) ń fi Ọjọ́ Àjíǹde búra. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 75

وَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلنَّفۡسِ ٱللَّوَّامَةِ

Mo tún ń fi ẹ̀mí tó máa dá ara rẹ̀ ní ẹ̀bi búra. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 75

أَيَحۡسَبُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَلَّن نَّجۡمَعَ عِظَامَهُۥ

Ṣé ènìyàn lérò pé A kò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni? info
التفاسير:

external-link copy
4 : 75

بَلَىٰ قَٰدِرِينَ عَلَىٰٓ أَن نُّسَوِّيَ بَنَانَهُۥ

Rárá. (À ń jẹ́) Alágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba. info

1.Àwọn ọmọníka ọwọ́ àti ọmọníka ẹsẹ̀, ọ̀tún rẹ̀ àti òsì rẹ̀. Ẹ tún wo sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:60-61 àti sūrah al-Mọ̄‘rij; 70:40-41.

التفاسير:

external-link copy
5 : 75

بَلۡ يُرِيدُ ٱلۡإِنسَٰنُ لِيَفۡجُرَ أَمَامَهُۥ

Rárá ènìyàn fẹ́ máa ṣe aburú lọ bẹ́ẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀ info
التفاسير:

external-link copy
6 : 75

يَسۡـَٔلُ أَيَّانَ يَوۡمُ ٱلۡقِيَٰمَةِ

ni ó fi ń bèèrè pé: “Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?” info
التفاسير:

external-link copy
7 : 75

فَإِذَا بَرِقَ ٱلۡبَصَرُ

Nígbà tí ojú bá rí ìdààmú tó sì yà sílẹ̀ tí kò lè padé, info
التفاسير:

external-link copy
8 : 75

وَخَسَفَ ٱلۡقَمَرُ

àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn, info
التفاسير:

external-link copy
9 : 75

وَجُمِعَ ٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ

àti (nígbà) tí wọ́n bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn tí ìmọ́lẹ̀ méjèèjì pòóró, info
التفاسير:

external-link copy
10 : 75

يَقُولُ ٱلۡإِنسَٰنُ يَوۡمَئِذٍ أَيۡنَ ٱلۡمَفَرُّ

ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: “Níbo ni ibùsásí wà?” info
التفاسير:

external-link copy
11 : 75

كَلَّا لَا وَزَرَ

Rárá, kò sí ibùsásí. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 75

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡمُسۡتَقَرُّ

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 75

يُنَبَّؤُاْ ٱلۡإِنسَٰنُ يَوۡمَئِذِۭ بِمَا قَدَّمَ وَأَخَّرَ

Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun tó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
14 : 75

بَلِ ٱلۡإِنسَٰنُ عَلَىٰ نَفۡسِهِۦ بَصِيرَةٞ

Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀, info
التفاسير:

external-link copy
15 : 75

وَلَوۡ أَلۡقَىٰ مَعَاذِيرَهُۥ

ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá. info
التفاسير:

external-link copy
16 : 75

لَا تُحَرِّكۡ بِهِۦ لِسَانَكَ لِتَعۡجَلَ بِهِۦٓ

Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 75

إِنَّ عَلَيۡنَا جَمۡعَهُۥ وَقُرۡءَانَهُۥ

Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
18 : 75

فَإِذَا قَرَأۡنَٰهُ فَٱتَّبِعۡ قُرۡءَانَهُۥ

Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 75

ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا بَيَانَهُۥ

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 75

كَلَّا بَلۡ تُحِبُّونَ ٱلۡعَاجِلَةَ

Kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé ni. info
التفاسير:

external-link copy
21 : 75

وَتَذَرُونَ ٱلۡأٓخِرَةَ

Ẹ sì ń gbé ọ̀run jù sílẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 75

وُجُوهٞ يَوۡمَئِذٖ نَّاضِرَةٌ

Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú). info
التفاسير:

external-link copy
23 : 75

إِلَىٰ رَبِّهَا نَاظِرَةٞ

Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò. info
التفاسير:

external-link copy
24 : 75

وَوُجُوهٞ يَوۡمَئِذِۭ بَاسِرَةٞ

Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
25 : 75

تَظُنُّ أَن يُفۡعَلَ بِهَا فَاقِرَةٞ

(Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé wọ́n máa fi aburú kan òhun. info
التفاسير:

external-link copy
26 : 75

كَلَّآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلتَّرَاقِيَ

Kò rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò. info
التفاسير:

external-link copy
27 : 75

وَقِيلَ مَنۡۜ رَاقٖ

A sì máa sọ pé: “Ǹjẹ́ olùpọfọ̀ kan wà bí (tí ó máa pọfọ̀ láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)? info
التفاسير:

external-link copy
28 : 75

وَظَنَّ أَنَّهُ ٱلۡفِرَاقُ

Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé. info
التفاسير:

external-link copy
29 : 75

وَٱلۡتَفَّتِ ٱلسَّاقُ بِٱلسَّاقِ

Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun. info
التفاسير:

external-link copy
30 : 75

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡمَسَاقُ

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn. info
التفاسير:

external-link copy
31 : 75

فَلَا صَدَّقَ وَلَا صَلَّىٰ

Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun. info
التفاسير:

external-link copy
32 : 75

وَلَٰكِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ

Ṣùgbọ́n ó pe òdodo ní irọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i. info
التفاسير:

external-link copy
33 : 75

ثُمَّ ذَهَبَ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ يَتَمَطَّىٰٓ

Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí. info
التفاسير:

external-link copy
34 : 75

أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰ

(Ìparun nílé ayé) ló tọ́ sí ọ jùlọ (lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ wọ̀nyẹn). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ. info
التفاسير:

external-link copy
35 : 75

ثُمَّ أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰٓ

Lẹ́yìn náà, (Iná) ló tọ́ sí ọ jùlọ (ní ọ̀run). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ. info
التفاسير:

external-link copy
36 : 75

أَيَحۡسَبُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَن يُتۡرَكَ سُدًى

Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni? info
التفاسير:

external-link copy
37 : 75

أَلَمۡ يَكُ نُطۡفَةٗ مِّن مَّنِيّٖ يُمۡنَىٰ

Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni? info
التفاسير:

external-link copy
38 : 75

ثُمَّ كَانَ عَلَقَةٗ فَخَلَقَ فَسَوَّىٰ

Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn. info
التفاسير:

external-link copy
39 : 75

فَجَعَلَ مِنۡهُ ٱلزَّوۡجَيۡنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰٓ

(Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti ara rẹ̀, akọ àti abo. info
التفاسير:

external-link copy
40 : 75

أَلَيۡسَ ذَٰلِكَ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحۡـِۧيَ ٱلۡمَوۡتَىٰ

Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí? info
التفاسير: