クルアーンの対訳 - ヨルバ語対訳 - Abu Rahima Mikhail

Al-Muddathir

external-link copy
1 : 74

يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمُدَّثِّرُ

Ìwọ olùdaṣọbora. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 74

قُمۡ فَأَنذِرۡ

Dìde kí o ṣèkìlọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 74

وَرَبَّكَ فَكَبِّرۡ

Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 74

وَثِيَابَكَ فَطَهِّرۡ

Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 74

وَٱلرُّجۡزَ فَٱهۡجُرۡ

Òrìṣà ni kí o jìnnà sí. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 74

وَلَا تَمۡنُن تَسۡتَكۡثِرُ

Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 74

وَلِرَبِّكَ فَٱصۡبِرۡ

Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 74

فَإِذَا نُقِرَ فِي ٱلنَّاقُورِ

Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, info
التفاسير:

external-link copy
9 : 74

فَذَٰلِكَ يَوۡمَئِذٖ يَوۡمٌ عَسِيرٌ

ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira, info
التفاسير:

external-link copy
10 : 74

عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ غَيۡرُ يَسِيرٖ

tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 74

ذَرۡنِي وَمَنۡ خَلَقۡتُ وَحِيدٗا

Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan (ìyẹn nínú ikùn ìyá rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
12 : 74

وَجَعَلۡتُ لَهُۥ مَالٗا مَّمۡدُودٗا

Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá info
التفاسير:

external-link copy
13 : 74

وَبَنِينَ شُهُودٗا

àti àwọn ọmọkúnrin tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 74

وَمَهَّدتُّ لَهُۥ تَمۡهِيدٗا

Mo sì fi àyè ìrọ̀rùn gbá a dáadáa. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 74

ثُمَّ يَطۡمَعُ أَنۡ أَزِيدَ

Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún. info
التفاسير:

external-link copy
16 : 74

كَلَّآۖ إِنَّهُۥ كَانَ لِأٓيَٰتِنَا عَنِيدٗا

Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 74

سَأُرۡهِقُهُۥ صَعُودًا

Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná)[1]. info

[1] Orúkọ àpáta ńlá kan nínú Iná ni Sọ‘ūd. Kèfèrí yóò máa pọ́n òkè náà láààrin àádọ́rin ọdún ní àpọ́njábọ́. Ìdí nìyí tí wọ́n fi pe ìyà náà ní ìyà pọ́nkèpọ́nkè.

التفاسير:

external-link copy
18 : 74

إِنَّهُۥ فَكَّرَ وَقَدَّرَ

Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀). info
التفاسير: