クルアーンの対訳 - ヨルバ語対訳 - Abu Rahima Mikhail

Al-Qamar

external-link copy
1 : 54

ٱقۡتَرَبَتِ ٱلسَّاعَةُ وَٱنشَقَّ ٱلۡقَمَرُ

Àkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì).[1] info

[1] Ìyẹn ṣẹlẹ̀ ní àsìkò Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ bèèrè fún àmì ìyanu lọ́wọ́ rẹ̀.

التفاسير:

external-link copy
2 : 54

وَإِن يَرَوۡاْ ءَايَةٗ يُعۡرِضُواْ وَيَقُولُواْ سِحۡرٞ مُّسۡتَمِرّٞ

Tí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: “Idán kan tó máa parẹ́ (ni èyí).”[1] info

[1] Ìtúmọ̀ mìíràn fún “sihrun mustamirr” idán kan tó lágbára (ni èyí).

التفاسير:

external-link copy
3 : 54

وَكَذَّبُواْ وَٱتَّبَعُوٓاْ أَهۡوَآءَهُمۡۚ وَكُلُّ أَمۡرٖ مُّسۡتَقِرّٞ

Wọ́n pè é ní irọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn. [1] info

[1] Ìtúmọ̀ mìíràn fún “wa kullu ’amrin mustaƙirr” Gbogbo ìṣe ẹ̀dá ló ní ìkángun.

التفاسير:

external-link copy
4 : 54

وَلَقَدۡ جَآءَهُم مِّنَ ٱلۡأَنۢبَآءِ مَا فِيهِ مُزۡدَجَرٌ

Dájúdájú wáàsí tí ó ń kọ aburú[1] wà nínú àwọn ìró tó dé bá wọn. info

[1] “Muzdajar” wáàsí tó le tó kún fún ìṣẹ̀rùbà àti àpẹ̀ẹrẹ ìjìyà tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn ọ̀tá òdodo.

التفاسير:

external-link copy
5 : 54

حِكۡمَةُۢ بَٰلِغَةٞۖ فَمَا تُغۡنِ ٱلنُّذُرُ

(al-Ƙur’ān sì ni) ọgbọ́n tó péye pátápátá; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 54

فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡۘ يَوۡمَ يَدۡعُ ٱلدَّاعِ إِلَىٰ شَيۡءٖ نُّكُرٍ

Ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde), info
التفاسير: