1. Ìyẹn nígbà tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - wà nílé ayé ṣíwájú kí ó tó kú.
1. Ìyẹn olùjẹ́rìí méjì láààrin àwọn mùsùlùmí, bí ó bá jẹ́ pé ìpọ́kàkà ikú ká a mọ́nú ìlú. 2. Ìyẹn olùjẹ́rìí méjì láààrin àwọn tí ìrìn-àjò dìjọ pa wọ́n pọ̀, yálà mùsùlùmí tàbí ẹlòmíìràn bí ó bá jẹ́ pé ìpọ́kàkà ikú ká a mọ́ orí ìrìn-àjò.
1. Tàbí “kí àwọn méjì mìíràn nínú ẹbí òkú tí wọ́n lè da ẹrí jíjẹ́ àwọn méjèèjì àkọ́kọ́ nù”.
1. Òfin yìí, òfin àsọọ́lẹ̀ lórí ogún, igun kan nínú àwọn onímọ̀ sọ pé, wọ́n ti pa ìdájọ́ rẹ̀ rẹ́, àmọ́ igun kejì sọ pé, wọn kò pa ìdájọ́ rẹ̀ rẹ́.