Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail

Al-Lay'l

external-link copy
1 : 92

وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَغۡشَىٰ

Allāhu fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 92

وَٱلنَّهَارِ إِذَا تَجَلَّىٰ

Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n búra. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 92

وَمَا خَلَقَ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰٓ

Ó tún fi Ẹni tí Ó dá akọ àti abo búra.[1] info

1. Allāhu Ẹlẹ́dàá ni Ẹni tí Ó dá akọ àti abo. Ó sì ń fi ara Rẹ̀ búra.

التفاسير:

external-link copy
4 : 92

إِنَّ سَعۡيَكُمۡ لَشَتَّىٰ

Dájúdájú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni iṣẹ́ yín. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 92

فَأَمَّا مَنۡ أَعۡطَىٰ وَٱتَّقَىٰ

Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu), info
التفاسير:

external-link copy
6 : 92

وَصَدَّقَ بِٱلۡحُسۡنَىٰ

(tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní òdodo, info
التفاسير:

external-link copy
7 : 92

فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلۡيُسۡرَىٰ

A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 92

وَأَمَّا مَنۢ بَخِلَ وَٱسۡتَغۡنَىٰ

Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni tó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run, info
التفاسير:

external-link copy
9 : 92

وَكَذَّبَ بِٱلۡحُسۡنَىٰ

(tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní irọ́, info
التفاسير:

external-link copy
10 : 92

فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلۡعُسۡرَىٰ

A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 92

وَمَا يُغۡنِي عَنۡهُ مَالُهُۥٓ إِذَا تَرَدَّىٰٓ

Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá parun, tí ó já bọ́ (sínú Iná). info
التفاسير:

external-link copy
12 : 92

إِنَّ عَلَيۡنَا لَلۡهُدَىٰ

Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 92

وَإِنَّ لَنَا لَلۡأٓخِرَةَ وَٱلۡأُولَىٰ

Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 92

فَأَنذَرۡتُكُمۡ نَارٗا تَلَظَّىٰ

Nítorí náà, Mo ti fi Iná tó ń jò fòfò kìlọ̀ fún yín. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 92

لَا يَصۡلَىٰهَآ إِلَّا ٱلۡأَشۡقَى

Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú, info
التفاسير:

external-link copy
16 : 92

ٱلَّذِي كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ

ẹni tí ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 92

وَسَيُجَنَّبُهَا ٱلۡأَتۡقَى

Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu), info
التفاسير:

external-link copy
18 : 92

ٱلَّذِي يُؤۡتِي مَالَهُۥ يَتَزَكَّىٰ

ẹni tó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
19 : 92

وَمَا لِأَحَدٍ عِندَهُۥ مِن نِّعۡمَةٖ تُجۡزَىٰٓ

Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni, info
التفاسير:

external-link copy
20 : 92

إِلَّا ٱبۡتِغَآءَ وَجۡهِ رَبِّهِ ٱلۡأَعۡلَىٰ

bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ. info
التفاسير:

external-link copy
21 : 92

وَلَسَوۡفَ يَرۡضَىٰ

Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rere rẹ̀). info
التفاسير: