Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail

external-link copy
6 : 47

وَيُدۡخِلُهُمُ ٱلۡجَنَّةَ عَرَّفَهَا لَهُمۡ

Ó máa fi wọ́n wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí Ó ti fi mọ̀ wọ́n.[1] info

1. Allāhu - Onímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba - ti fi Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀ mọ̀ wá pẹ̀lú oríkì kíkún àti àkàwé tó lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ọkàn wa fi ń jẹ̀rankàn rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa fi ṣíjú àánú Rẹ̀ wò wá ní ọjọ́ Àjíǹde.

التفاسير: