Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail

Yaasiin

external-link copy
1 : 36

يسٓ

Yā sīn (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

التفاسير:

external-link copy
2 : 36

وَٱلۡقُرۡءَانِ ٱلۡحَكِيمِ

(Allāhu) fi Al-Ƙur’ān tí ó kún fún ọgbọ́n búra.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:1

التفاسير:

external-link copy
3 : 36

إِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 36

عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ

(O) wà lórí ọ̀nà tààrà (’Islām). info
التفاسير:

external-link copy
5 : 36

تَنزِيلَ ٱلۡعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ

(Al-Ƙur’ān jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run info
التفاسير:

external-link copy
6 : 36

لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أُنذِرَ ءَابَآؤُهُمۡ فَهُمۡ غَٰفِلُونَ

nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, (àwọn) tí wọn kò ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn bàbá wọn rí. Nítorí náà, afọ́núfọ́ra sì ni wọ́n (nípa ìmọ̀nà).[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọsọs; 28:46.

التفاسير:

external-link copy
7 : 36

لَقَدۡ حَقَّ ٱلۡقَوۡلُ عَلَىٰٓ أَكۡثَرِهِمۡ فَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ

Dájúdájú ọ̀rọ̀ náà ti kò lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lórí; wọn kò sì níí gbàgbọ́. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 36

إِنَّا جَعَلۡنَا فِيٓ أَعۡنَٰقِهِمۡ أَغۡلَٰلٗا فَهِيَ إِلَى ٱلۡأَذۡقَانِ فَهُم مُّقۡمَحُونَ

Dájúdájú Àwa ti kó ẹ̀wọ̀n sí wọn lọ́rùn (mọ́ ọwọ́ wọn). Ó sì ga dé àgbọ̀n (wọn). Wọ́n sì gà wọ́n lọ́rùn sókè. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 36

وَجَعَلۡنَا مِنۢ بَيۡنِ أَيۡدِيهِمۡ سَدّٗا وَمِنۡ خَلۡفِهِمۡ سَدّٗا فَأَغۡشَيۡنَٰهُمۡ فَهُمۡ لَا يُبۡصِرُونَ

Àti pé Àwa fi gàgá kan síwájú wọn, gàgá kan sẹ́yìn wọn; A bò wọ́n lójú, wọn kò sì ríran. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 36

وَسَوَآءٌ عَلَيۡهِمۡ ءَأَنذَرۡتَهُمۡ أَمۡ لَمۡ تُنذِرۡهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ

Bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn; wọn kò níí gbàgbọ́.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:6.

التفاسير:

external-link copy
11 : 36

إِنَّمَا تُنذِرُ مَنِ ٱتَّبَعَ ٱلذِّكۡرَ وَخَشِيَ ٱلرَّحۡمَٰنَ بِٱلۡغَيۡبِۖ فَبَشِّرۡهُ بِمَغۡفِرَةٖ وَأَجۡرٖ كَرِيمٍ

Ẹni tí ìkìlọ̀ rẹ (máa wúlò fún) ni ẹni tí ó tẹ̀lé Ìrántí (al-Ƙur’ān), tí ó sì páyà Àjọkẹ́-ayé ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, fún un ní ìró ìdùnnú nípa àforíjìn àti ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 36

إِنَّا نَحۡنُ نُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَنَكۡتُبُ مَا قَدَّمُواْ وَءَاثَٰرَهُمۡۚ وَكُلَّ شَيۡءٍ أَحۡصَيۡنَٰهُ فِيٓ إِمَامٖ مُّبِينٖ

Dájúdájú Àwa l’À ń sọ àwọn òkú di alàyè. A sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n tì síwájú àti orípa (iṣẹ́ ọwọ́) wọn. Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan tó yanjú. info
التفاسير: