1. Okùnfà āyah yìí ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah ń sọ fún Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé, “Tí o bá fi lè pa ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà àwọn bàbá rẹ tì, o ti ṣìnà nìyẹn.” Allāhu sì sọ āyah kalẹ̀.
1. Àwọn aláìgbàgbọ́ yóò máa ṣojú kòkòrò sí ìronúpìwàdà àti ìpadà sí ilé ayé ní Ọjọ́ Àjíǹde nígbà tí àìgbàgbọ́ wọn bá di ìyà ńlá fún wọn. Àmọ́ Allāhu kò níí fún wọn ní àyè láti lọ ronú pìwàdà tàbí láti padà sí ilé ayé.