Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail

Numero di pagina:close

external-link copy
59 : 24

وَإِذَا بَلَغَ ٱلۡأَطۡفَٰلُ مِنكُمُ ٱلۡحُلُمَ فَلۡيَسۡتَـٔۡذِنُواْ كَمَا ٱسۡتَـٔۡذَنَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ ءَايَٰتِهِۦۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ

Nígbà tí àwọn ọmọdé yín bá sì bàlágà[1], kí àwọn náà máa gba ìyọ̀ǹda gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe gba ìyọ̀ǹda. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’; 4:6.

التفاسير:

external-link copy
60 : 24

وَٱلۡقَوَٰعِدُ مِنَ ٱلنِّسَآءِ ٱلَّٰتِي لَا يَرۡجُونَ نِكَاحٗا فَلَيۡسَ عَلَيۡهِنَّ جُنَاحٌ أَن يَضَعۡنَ ثِيَابَهُنَّ غَيۡرَ مُتَبَرِّجَٰتِۭ بِزِينَةٖۖ وَأَن يَسۡتَعۡفِفۡنَ خَيۡرٞ لَّهُنَّۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٞ

Àwọn tó ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí nínú àwọn obìnrin, àwọn tí kò retí àti lọ́kọ mọ́ (tí kò retí ìbálòpò oorun ìfẹ́ mọ́), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn láti bọ́ àwọn aṣọ jilbāb wọn sílẹ̀, tí wọn kò sì níí ṣe àfihàn ọ̀ṣọ́ kan síta. Kí wọ́n kóra wọn ní ìjánu (kí wọ́n máa wọ aṣọ jilbāb wọn lọ bẹ́ẹ̀) lóore jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
61 : 24

لَّيۡسَ عَلَى ٱلۡأَعۡمَىٰ حَرَجٞ وَلَا عَلَى ٱلۡأَعۡرَجِ حَرَجٞ وَلَا عَلَى ٱلۡمَرِيضِ حَرَجٞ وَلَا عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمۡ أَن تَأۡكُلُواْ مِنۢ بُيُوتِكُمۡ أَوۡ بُيُوتِ ءَابَآئِكُمۡ أَوۡ بُيُوتِ أُمَّهَٰتِكُمۡ أَوۡ بُيُوتِ إِخۡوَٰنِكُمۡ أَوۡ بُيُوتِ أَخَوَٰتِكُمۡ أَوۡ بُيُوتِ أَعۡمَٰمِكُمۡ أَوۡ بُيُوتِ عَمَّٰتِكُمۡ أَوۡ بُيُوتِ أَخۡوَٰلِكُمۡ أَوۡ بُيُوتِ خَٰلَٰتِكُمۡ أَوۡ مَا مَلَكۡتُم مَّفَاتِحَهُۥٓ أَوۡ صَدِيقِكُمۡۚ لَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٌ أَن تَأۡكُلُواْ جَمِيعًا أَوۡ أَشۡتَاتٗاۚ فَإِذَا دَخَلۡتُم بُيُوتٗا فَسَلِّمُواْ عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمۡ تَحِيَّةٗ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ مُبَٰرَكَةٗ طَيِّبَةٗۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ

Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà láti jẹun nínú ilé yín, tàbí ilé àwọn bàbá yín, tàbí ilé àwọn ìyá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin ìyá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin ìyá yín, tàbí (ilé) tí ẹ ní ìkápá lórí àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, tàbí (ilé) ọ̀rẹ́ yín. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín láti jẹun papọ̀ tàbí ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, tí ẹ bá wọ àwọn inú ilé kan, ẹ sálámọ̀ síra yín. (Èyí jẹ́) ìkíni ìbùkún tó dára láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè. info
التفاسير: