Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail

An-Nah'l

external-link copy
1 : 16

أَتَىٰٓ أَمۡرُ ٱللَّهِ فَلَا تَسۡتَعۡجِلُوهُۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ

Àṣẹ Allāhu dé tán. Ẹ ma wulẹ̀ wá a pẹ̀lú ìkánjú. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 16

يُنَزِّلُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ بِٱلرُّوحِ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦٓ أَنۡ أَنذِرُوٓاْ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱتَّقُونِ

(Allāhu) ń fi àṣẹ Rẹ̀ sọ mọlāika (Jibrīl) kalẹ̀ láti máa mú ìmísí wá díẹ̀díẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ fún) nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè fi ṣe ìkìlọ̀ pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.” info
التفاسير:

external-link copy
3 : 16

خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۚ تَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ

Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 16

خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِن نُّطۡفَةٖ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٞ مُّبِينٞ

Ó dá ènìyàn láti inú àtọ̀. (Ènìyàn) sì di olùjiyàn pọ́nńbélé (nípa Àjíǹde). info
التفاسير:

external-link copy
5 : 16

وَٱلۡأَنۡعَٰمَ خَلَقَهَاۖ لَكُمۡ فِيهَا دِفۡءٞ وَمَنَٰفِعُ وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ

Àwọn ẹran-ọ̀sìn, Ó ṣẹ̀dá wọn (fún yín). Aṣọ òtútù àti àwọn àǹfààní (mìíràn) ń bẹ fún yín lára wọn. Àti pé ẹ̀ ń jẹ nínú wọn. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 16

وَلَكُمۡ فِيهَا جَمَالٌ حِينَ تُرِيحُونَ وَحِينَ تَسۡرَحُونَ

Ọ̀ṣọ́ tún ń bẹ fún yín lára wọn nígbà tí ẹ bá ń dà wọ́n lọ (sí ilé wọn) àti nígbà tí ẹ bá ń kó wọn jáde lọ jẹko.[1] info

1. Èyí ni pé, dída ẹran-ọ̀sìn lọ bọ̀, ó jẹ́ ọ̀ṣọ́ fún olówó rẹ̀ fún wí pé àwọn ènìyàn yóò mọ olówó ẹran-ọ̀sìn sí ẹni tí àṣírí rẹ̀ bò tàbí ọlọ́rọ̀.

التفاسير: