Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Abu Rahimah Mikael

Luk'maan

external-link copy
1 : 31

الٓمٓ

’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

التفاسير:

external-link copy
2 : 31

تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡحَكِيمِ

Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tí ó kún fún ọgbọ́n.[1] info

1. Pípe al-Ƙur’ān ní “hakīm” túmọ̀ sí tírà tí ó kún fún ọgbọ́n, tírà tí ó ń ṣe ìdájọ́ àti tírà tí wọ́n to àwọn āyah rẹ̀ àti sūrah rẹ̀ tó gún régé láì sí ìdàrúdàpọ̀ àti ìtakora kan nínú rẹ̀.

التفاسير:

external-link copy
3 : 31

هُدٗى وَرَحۡمَةٗ لِّلۡمُحۡسِنِينَ

(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún àwọn olùṣe-rere; info
التفاسير:

external-link copy
4 : 31

ٱلَّذِينَ يُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ يُوقِنُونَ

àwọn tó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 31

أُوْلَٰٓئِكَ عَلَىٰ هُدٗى مِّن رَّبِّهِمۡۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 31

وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَشۡتَرِي لَهۡوَ ٱلۡحَدِيثِ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَيَتَّخِذَهَا هُزُوًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ

Ó wà nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń ra ọ̀rọ̀ eré[1] láti fi ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àìnímọ̀ àti nítorí kí ó lè sọ ẹ̀sìn di yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún. info

1. Ọ̀rọ̀ eré ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ́ orin, odù irọ́, ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ àti ìsọkúsọ. Èyí sì lè jẹ́ odù ifá, orin àlùjó, ọ̀rọ̀ ìròrí (philosophy) àti fíìmù (tíátà).

التفاسير:

external-link copy
7 : 31

وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا وَلَّىٰ مُسۡتَكۡبِرٗا كَأَن لَّمۡ يَسۡمَعۡهَا كَأَنَّ فِيٓ أُذُنَيۡهِ وَقۡرٗاۖ فَبَشِّرۡهُ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ

Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa pẹ̀yìndà ní ti ìgbéraga, àfi bí ẹni pé kò gbọ́ ọ, àfi bí ẹni pé èdídí wà nínú etí rẹ̀ méjèèjì. Nítorí náà, fún un ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 31

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ جَنَّٰتُ ٱلنَّعِيمِ

Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 31

خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٗاۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní ti òdodo. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 31

خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ بِغَيۡرِ عَمَدٖ تَرَوۡنَهَاۖ وَأَلۡقَىٰ فِي ٱلۡأَرۡضِ رَوَٰسِيَ أَن تَمِيدَ بِكُمۡ وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَآبَّةٖۚ وَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوۡجٖ كَرِيمٍ

Ó dá àwọn sánmọ̀ láì ní òpó tí ẹ lè rí. Ó sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ yín lẹ́sẹ̀. Ó fọ́n gbogbo n̄ǹkan abẹ̀mí ká sórí ilẹ̀. A tún sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, A sì fi mú gbogbo oríṣiríṣi èso dáadáa hù jáde láti inú ilẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 31

هَٰذَا خَلۡقُ ٱللَّهِ فَأَرُونِي مَاذَا خَلَقَ ٱلَّذِينَ مِن دُونِهِۦۚ بَلِ ٱلظَّٰلِمُونَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ

Èyí ni ẹ̀dá ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ fi ohun tí àwọn mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀ dá hàn mí! Rárá o! Àwọn alábòsí wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé ni. info
التفاسير: