1. Pípe al-Ƙur’ān ní “hakīm” túmọ̀ sí tírà tí ó kún fún ọgbọ́n, tírà tí ó ń ṣe ìdájọ́ àti tírà tí wọ́n to àwọn āyah rẹ̀ àti sūrah rẹ̀ tó gún régé láì sí ìdàrúdàpọ̀ àti ìtakora kan nínú rẹ̀.
1. Ọ̀rọ̀ eré ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ́ orin, odù irọ́, ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ àti ìsọkúsọ. Èyí sì lè jẹ́ odù ifá, orin àlùjó, ọ̀rọ̀ ìròrí (philosophy) àti fíìmù (tíátà).