Traduction des sens du Noble Coran - La traduction en yorouba - Aboû Raḥîmah Mickaël

external-link copy
37 : 7

فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوۡ كَذَّبَ بِـَٔايَٰتِهِۦٓۚ أُوْلَٰٓئِكَ يَنَالُهُمۡ نَصِيبُهُم مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُنَا يَتَوَفَّوۡنَهُمۡ قَالُوٓاْ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِۖ قَالُواْ ضَلُّواْ عَنَّا وَشَهِدُواْ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ أَنَّهُمۡ كَانُواْ كَٰفِرِينَ

Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí tó pe àwọn āyah Rẹ̀ ní irọ́? Ìpín àwọn wọ̀nyẹn nínú kádàrá yóò máa tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa yóò wá bá wọn, tí wọn yóò gba ẹ̀mí wọn. Wọn yó sì sọ pé: “Níbo ni àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀yin ń pè lẹ́yìn Allāhu wà?” Wọn yóò wí pé: “Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́.” Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́.” info
التفاسير: