1. Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún ìjọ ọ̀tún, Ọgbà Iná sì wá fún ìjọ òsì. Àmọ́, Allāhu - tó ga jùlọ - ṣe àtúnpín ìjọ ọ̀tún sí ìjọ ọ̀tún àti ìjọ aṣíwájú nítorí pé, ìgbádùn ìkíní kejì yàtọ̀ gan-an síra wọn.
1. Àwọn ẹni àkọ́kọ́ dúró fún àwọn ènìyàn láti àsìkò Ànábì Ādam títí di àsìkò Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -. Àwọn ẹni Ìkẹ́yìn sì dúró fún ìjọ Ànábì wa nìkan - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
1. Ẹ tún wo sūrah al-Mọ̄‘rij; 70:40-41 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:3-4.
1. “Mọwāƙi‘u-nnujūm” tún lè túmọ̀ sí “àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ nínú sánmọ̀”. Nítorí náà, ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí nìyí: “Nítorí náà, Mò ń fi àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ búra.”
1. Ìyẹn ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ ń dúpẹ́ fún ìràwọ̀ nítorí pé, wọ́n gbàgbọ́ pé òhun l’ó ń rọ̀jò lẹ́yìn Allāhu. Irọ́ àti àìgbàgbọ́ nínú Allāhu ni èyí. Allāhu - tó ga jùlọ - ni Ẹni t’Ó ń rọ̀jò fún ẹ̀dá Rẹ̀.