Traduction des sens du Noble Coran - La traduction en yorouba - Aboû Raḥîmah Mickaël

Al-An'kabuut

external-link copy
1 : 29

الٓمٓ

’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

التفاسير:

external-link copy
2 : 29

أَحَسِبَ ٱلنَّاسُ أَن يُتۡرَكُوٓاْ أَن يَقُولُوٓاْ ءَامَنَّا وَهُمۡ لَا يُفۡتَنُونَ

Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lérò pé A óò fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ pé: “A gbàgbọ́”, tí A ò sì níí dán wọn wò? info
التفاسير:

external-link copy
3 : 29

وَلَقَدۡ فَتَنَّا ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ فَلَيَعۡلَمَنَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ صَدَقُواْ وَلَيَعۡلَمَنَّ ٱلۡكَٰذِبِينَ

A kúkú ti dán àwọn tó ṣíwájú wọn wò. Nítorí náà, dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn tó sọ òdodo. Dájúdájú Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 29

أَمۡ حَسِبَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن يَسۡبِقُونَاۚ سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ

Àbí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé àwọn máa mórí bọ́ mọ́ Wa lọ́wọ́ ni? Ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 29

مَن كَانَ يَرۡجُواْ لِقَآءَ ٱللَّهِ فَإِنَّ أَجَلَ ٱللَّهِ لَأٓتٖۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Allāhu, dájúdájú àkókò Allāhu kúkú ń bọ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 29

وَمَن جَٰهَدَ فَإِنَّمَا يُجَٰهِدُ لِنَفۡسِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَنِيٌّ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìyànjú, ó ń gbìyànjú fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير: