Traduction des sens du Noble Coran - La traduction en yorouba - Aboû Raḥîmah Mickaël

Al-Maahuun

external-link copy
1 : 107

أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يُكَذِّبُ بِٱلدِّينِ

Sọ fún mi nípa ẹni tó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san ní irọ́! info
التفاسير:

external-link copy
2 : 107

فَذَٰلِكَ ٱلَّذِي يَدُعُّ ٱلۡيَتِيمَ

Ìyẹn ni ẹni tó ń lé ọmọ-òrukàn dànù. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 107

وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ

Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 107

فَوَيۡلٞ لِّلۡمُصَلِّينَ

Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) tó ń kírun;[1] info

1. Pẹ̀lú ìrun wákàtí márààrún lójoojúmọ́ ní àsìkò rẹ̀, ó ti run gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ dànù. Ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ-àforíjìn l’ó máa run àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá dànù.

التفاسير:

external-link copy
5 : 107

ٱلَّذِينَ هُمۡ عَن صَلَاتِهِمۡ سَاهُونَ

àwọn tó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀; info
التفاسير:

external-link copy
6 : 107

ٱلَّذِينَ هُمۡ يُرَآءُونَ

àwọn tó ń ṣe ṣekárími; info
التفاسير:

external-link copy
7 : 107

وَيَمۡنَعُونَ ٱلۡمَاعُونَ

àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn). info
التفاسير: