1. "Iṣẹ́ Mi" ìyẹn ni iṣẹ́ tí Allāhu fi rán Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - sí ìjọ rẹ̀. "Ọ̀rọ̀ Mi" ìyẹn ni ìbánisọ̀rọ̀ tó wáyé láààrin Allāhu àti Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́yìn gàgá tààrà láì lọ́wọ́ mọlāika nínú.
1. Ilé àwọn arúfin nínú āyah yìí lè jẹ́ àbọ̀ àwọn arúfin ní ọ̀run. Èyí sì ni Iná
1. Āyah túmọ̀ sí ìpínrọ̀ nínú sūrah, àmì àti ẹ̀rí èyí tí Allāhu - tó ga jùlọ - sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo.