1. Oríṣi ìyà méjì wọ̀nyí ni Allāhu - tó ga jùlọ - fi jẹ ìjọ Ànábì Ṣu‘aeb - kí ọlà Allāhu má abá a -; ohùn igbe líle tó mi ilẹ̀ tìtì (sūrah Hūd; 11:94) àti ẹ̀ṣújò iná (sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:189).
1. Àwọn wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ, wọn kò gbàgbọ́ pé àìgbàgbọ́ l’ó kó ìparun bá àwọn bàbá wọn. Èrò-ọkàn wọn ni pé, bí ọ̀rọ̀ ilé ayé ṣe rí ni pé, ènìyàn máa jìyà, ó sì máa jọrọ̀. Èrò-ọkàn wọn yìí mú wọn won̄koko mọ́ ìbọ̀rìṣà. Àwọn náà sì di ẹni ìparun bíi tàwọn bàbá wọn.