Traducción de los significados del Sagrado Corán - Traducción Yoruba - Abu Rahima Mikael

Al-Bayyinah

external-link copy
1 : 98

لَمۡ يَكُنِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ وَٱلۡمُشۡرِكِينَ مُنفَكِّينَ حَتَّىٰ تَأۡتِيَهُمُ ٱلۡبَيِّنَةُ

Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn kò níí kúrò nínú àìgbàgbọ́ wọn títí di ìgbà tí ẹ̀rí tó yanjú yó fi máa dé ọ̀dọ̀ wọn. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 98

رَسُولٞ مِّنَ ٱللَّهِ يَتۡلُواْ صُحُفٗا مُّطَهَّرَةٗ

Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu yó (sì) máa ké àwọn tákàdá mímọ́. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 98

فِيهَا كُتُبٞ قَيِّمَةٞ

Àwọn ìwé òfin tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sì wà nínú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 98

وَمَا تَفَرَّقَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَةُ

Àwọn tí A fún ní tírà kò sì di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ẹ̀rí tó yanjú dé bá wọn. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 98

وَمَآ أُمِرُوٓاْ إِلَّا لِيَعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ حُنَفَآءَ وَيُقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤۡتُواْ ٱلزَّكَوٰةَۚ وَذَٰلِكَ دِينُ ٱلۡقَيِّمَةِ

Àwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un,[1] lẹ́ni tí yóò dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn. Kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì yọ Zakāh. Ìyẹn sì ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f 7:29.

التفاسير: