Traducción de los significados del Sagrado Corán - Traducción Yoruba - Abu Rahima Mikael

Número de página:close

external-link copy
14 : 9

قَٰتِلُوهُمۡ يُعَذِّبۡهُمُ ٱللَّهُ بِأَيۡدِيكُمۡ وَيُخۡزِهِمۡ وَيَنصُرۡكُمۡ عَلَيۡهِمۡ وَيَشۡفِ صُدُورَ قَوۡمٖ مُّؤۡمِنِينَ

Ẹ jà wọ́n lógun. Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà láti ọwọ́ yín. Ó máa yẹpẹrẹ wọn. Ó máa ràn yín lọ́wọ́ lórí wọn. Ó sì máa wo ọkàn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo sàn. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 9

وَيُذۡهِبۡ غَيۡظَ قُلُوبِهِمۡۗ وَيَتُوبُ ٱللَّهُ عَلَىٰ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ

Ó tún máa kó ìbínú ọkàn wọn lọ. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
16 : 9

أَمۡ حَسِبۡتُمۡ أَن تُتۡرَكُواْ وَلَمَّا يَعۡلَمِ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ جَٰهَدُواْ مِنكُمۡ وَلَمۡ يَتَّخِذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَا رَسُولِهِۦ وَلَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَلِيجَةٗۚ وَٱللَّهُ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ

Tàbí ẹ lérò pé A óò fi yín sílẹ̀ láì jẹ́ pé Allāhu ti ṣàfi hàn àwọn tó máa jagun ẹ̀sìn nínú yín, tí wọn kò sì ní ọ̀rẹ́ àyò kan lẹ́yìn Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo? Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 9

مَا كَانَ لِلۡمُشۡرِكِينَ أَن يَعۡمُرُواْ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ شَٰهِدِينَ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِم بِٱلۡكُفۡرِۚ أُوْلَٰٓئِكَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ وَفِي ٱلنَّارِ هُمۡ خَٰلِدُونَ

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu, nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àìgbàgbọ́ lórí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Iná. info
التفاسير:

external-link copy
18 : 9

إِنَّمَا يَعۡمُرُ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَأَقَامَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَى ٱلزَّكَوٰةَ وَلَمۡ يَخۡشَ إِلَّا ٱللَّهَۖ فَعَسَىٰٓ أُوْلَٰٓئِكَ أَن يَكُونُواْ مِنَ ٱلۡمُهۡتَدِينَ

Ẹni tí yóò máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu ni ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tó sì ń kírun, tó ń yọ Zakāh, kò sì páyà (òrìṣà kan) lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n kúkú wà nínú àwọn olùmọ̀nà. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 9

۞ أَجَعَلۡتُمۡ سِقَايَةَ ٱلۡحَآجِّ وَعِمَارَةَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ كَمَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَجَٰهَدَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۚ لَا يَسۡتَوُۥنَ عِندَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ

Ṣé ẹ máa ṣe fífún alálàájì ní omi mu àti ṣíṣe àmójútó Mọ́sálásí Haram ní ohun tó dọ́gba sí ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tó sì jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu? Wọn kò dọ́gba lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 9

ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡ أَعۡظَمُ دَرَجَةً عِندَ ٱللَّهِۚ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَآئِزُونَ

Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀,[1] tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu, wọ́n tóbi jùlọ ní ipò lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an sì ni olùjèrè. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’; 4:100.

التفاسير: