1. N̄ǹkan tí Allāhu - tó ga jùlọ - fi pààlà sáààrin Ọgbà Ìdẹ̀ra àti Ọgbà Iná ń jẹ́ orúkọ mẹ́ta nínú al-Ƙur’ān; hijāb, ‘urf àti sūr. 2. Àwọn ará orí gàgá “ ashābul-’a‘rọ̄f” ni àwọn tí òṣùwọ̀n iṣẹ́ rere àti òṣùwọ̀n iṣẹ́ aburú wọn dọ́gba síra wọn. Wọ́n kọ́kọ́ máa wà láààrin Ọgbà Ìdẹ̀ra àti Ọgbà Iná, lẹ́yìn náà, wọ́n máa padà wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.