Traducción de los significados del Sagrado Corán - Traducción Yoruba - Abu Rahima Mikael

external-link copy
12 : 17

وَجَعَلۡنَا ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ ءَايَتَيۡنِۖ فَمَحَوۡنَآ ءَايَةَ ٱلَّيۡلِ وَجَعَلۡنَآ ءَايَةَ ٱلنَّهَارِ مُبۡصِرَةٗ لِّتَبۡتَغُواْ فَضۡلٗا مِّن رَّبِّكُمۡ وَلِتَعۡلَمُواْ عَدَدَ ٱلسِّنِينَ وَٱلۡحِسَابَۚ وَكُلَّ شَيۡءٖ فَصَّلۡنَٰهُ تَفۡصِيلٗا

A ṣe alẹ́ àti ọ̀sán ní àmì méjì; A pa àmì alẹ́ rẹ́, A sì ṣe àmì ọ̀sán ní ìríran[1] nítorí kí ẹ lè wá oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (àwọn ọjọ́). Gbogbo n̄ǹkan ni A ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìfọ́síwẹ́wẹ́.² info

1. Àmì alẹ́ ni òṣùpá, àmì ọ̀sán ni òòrùn. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:114.

التفاسير: